Ìdálọ́lá fún Kudirat Abiola jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Tinubu sọ ní June 12

Ìdálọ́lá fún Kudirat Abiola jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Tinubu sọ ní June 12

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà, ọdún 2025 ni àyájọ́ ìjọba àwarawa pẹ̀lú ìrántí ètò ìdìbò tí MKO Abiola ti jáwé olúborí nínú ìdìbò Ààrẹ June 12, ọdún 1993.

Lọ́dọọdún sì ni àwọn Ààrẹ tó bá wà lórí àléfà, má ń bá aráàlú sọ̀rọ̀ láti ilé Ààrẹ.

Amọ ni ọdun yii, ile igbimọ aṣofin ni Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe ayajọ June 12, to si fi asiko naa kede awọn igbesẹ kan ti ijọba rẹ gbe.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Tinubu kede pe oun ti fi oye nla orilẹede Naijiria da awọn eeyan kan to ko ipa nla lasiko June 12 ọdun 1993 lọla.

Aarẹ Bola Tinubu fi oye nla da Kudirat Abiola, aya oloogbe Moshood Abiola, alaga ajọ eleto idibo (NEC) nigba naa, Humphrey Nwosu, to fi mọ igbakeji aarẹ nigba kan ri, Shehu Yar’Adua, pẹlu awọn yooku, lọla.
Tinubu kede eyi nigba to ba awọn araalu sọrọ fun ayajọ ijọba awarawa.

Bẹẹ ba gbagbe, Moshood Abiola ni wọn kede pe o bori eto idibo aarẹ ọdun 1993.
“Bi a ṣe n ṣe ayajọ ọdun mẹrindinlọgbọn ijọba awaarawa, ohun to tọ ni ki a fi oye nla da awọn eeyan to ko ipa nla lati ri pe a ri ijọba awaarawa gba fun orilẹede wa, lọla” Tinubu sọ.

“Pẹlu eyi mo n kede fifi oye CFR da Kudirat Abiola lọla, fun ipa to ko ni June 12.”

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun fi oye CON da Nwosu ati oye GCFR da Shehu Musa Yar’Adua lọla.

Awọn yooku ti aarẹ fi oye da lọla ni Rear Admiral Ndubuisi Kanu (CON), Alhaji Balarabe Musa (CFR), Pa. Alfred Rewani (CFR), Bagauda Kaltho (OON), Chima Ubani (OON), Dr. Beko Ransome-Kuti (CON), Alao Aka Bashorun (CON), Chief Frank Kokori (CON), Emma Ezeazu (OON), Bamidele Aturu (OON), Fredrick Fasehun (CON), Ọjọgbọn Festus Iyayi (CON), Dr John Yima Sen (OON), Alhaja Sawaba Gambo (CON), Dr. Edwin Madunagu (CON), Dr. Alex Ibru (CON), Chief Bola Ige (CFR), Pa. Reuben Fasoranti (CFR), Sen. Ayo Fasanmi (CON), Sen. Polycarp Nwite (CON) ati Dr. Nurudeen Olowopopo (CON),” Aarẹ kede.

Yatọ si eyi, awọn eeyan mi ti aarẹ tun fi oye da lọla ni ajafẹtọ ọmọniyan ati agbẹjọro, Femi Falana, Agba onkọwe, Wole Soyinka, ati Bisọọbu ijọ Sokoto Diocese, Hassan Kukah.
Aarẹ Tinubu tun jẹ ko di mimọ pe, irọ to jina sina si otitọ ni pe oun fi ofin de ajọ INEC lati ma ṣe faaye gba idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun gẹgẹ bii iroyin kan ṣe gbe sita.

Aarẹ ni oun ko gbe igbesẹ kankan pe ki INEC ma faaye gba idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun.

“N ko sọ eyi rara pe ko ma si idasilẹ ẹgbẹ oṣelu tuntun.”

O ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, yoo jẹbi ọpọ ẹsun ti ko ba fi aye gba ki awọn eeyan darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.

O wa fi asiko naa ki awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun lati ipinlẹ Delta ati Akwa Ibom, “Ẹ kaabọ si ẹgbẹ itẹsiwaju.”

Bakan naa ni Tinubu ni oun ko ṣetan lati ṣe iranlọwọ fun ẹgbẹ oṣelu kankan lati to ile wọn nitori inu oun dun bi o ṣe n daru.

“O dun lati ma wo bi ile yin ṣe n daru.”

Aarẹ Bola Tinubu ni oun ṣeleri lati daabo bo ẹtọ awọn araalu lati sọ ohunkohun ti wọn ba fẹ sọ sita.

Aarẹ sọ fun awọn ẹsọ alabo lati ma ṣe dẹru ba ẹnikẹni to ba bu ẹnu atẹ lu iṣejọba rẹ.

“Ijọba awaarawa faaye gba ki eeyan ma sọ ohun to ba fẹ tabi fi iwọsi ransẹ si ijọba.

“Ẹ pe mi ni orukọ, ẹ pe mi ni ohun ti ẹ ba fẹ pe mi, nitori ijọba awaarawa sọ pe ẹ ni ẹtọ lati ṣe bẹ.”

Bakan naa ni aarẹ kesi awọn oloṣelu pe ki wọn faaye gba ijiroro dipo ki wọn ma a paṣẹ wa a tabi tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Aarẹ Bola Tinubu ni ileeṣẹ aarẹ ti forijin oloogbe ajafẹtọ ọmọniyan, Ken Saro Wiwa ati awọn mẹjọ mii ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Ogoni, ti wọn n pe ni Ogoni Nine.

Tinubu ṣapejuwe awọn eeyan yii gẹgẹ bii akọni fun orilẹede Naijiria, to si tun kede pe wọn yoo gbe ami ẹyẹ kalẹ ni orukọ wọn .

Awọn ọmọ eeyan yooku ni Saturday Dobee, Nordu Eawo, Daniel Gbooko, Paul Levera, Felix Nuate, Baribor Bera, Barinem Kiobel, ati John Kpuine.

“Bakan naa ni mo tun fun wọn ni ami ẹyẹ nla ti orilẹede Naijiria; Ken Saro Wiwa (CON), Saturday Dobee (OON), Nordu Eawo (OON), Daniel Gbooko (OON), Paul Levera (OON), Felix Nuate (OON), Baribor Bera (OON), Barinem Kiobel (OON), ati John Kpuine (OON).

“Mo ma lo agbara mi lati fi idarijin ijọba fun awọn mii ti a si ma kede orukọ wọn ni aipẹ yii.”

Saro Wiwa ati awọn akẹgbẹ rẹ ni wọn fẹsun ipaniyan kan, ti wọn si yẹgi fun wọn ni ọdun 1995 labẹ iṣejọba Oloogbe Sani Abacha