Kàyééfì! Rògbòdìyàn ní Òmù Àrán láàrin ọlọ́pàá, afurasí ọmọ Yahoo àti àwọn ọ̀dọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìfẹ̀hónuhan ńlá gbilẹ̀ nílùú ìlú Òmù-àrán ní ìjọba ìbílẹ̀ Irẹpọdun ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Ifẹhonuhan naa to bẹrẹ lọjọ Aìku, ọjọ Kẹdọgbọn oṣu karun un, to si tun tẹsiwaju ni Ọjọ Aje, Ọjọ kẹrindinlọgbọn osu karun un bakan naa.
Gẹgẹ bí iroyin tí a gbọ, Ọgbẹni Sẹgun to jẹ ọmọ bibi ilu Omu-aran ṣalaye pe Ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye.
Awọn eeyan diẹ farapa lasiko ifẹhonuhan naa gẹgẹ bii ohun ti a ri gbọ.
Segun ni lati bi ọjọ melo kan si asiko yii ni awọn ọlọpaa ti mu awọn ọdọ ni ilu naa, ti wọn si n fẹsun kan wọn pe wọn lọwọ si iwa ọdaran ori ẹrọ ayelujara .
O fikun pe ọrọ yii lo bi ọpọ awọn ọdọ ilu ninu ni pe ati awọn to n se Yahoo ati awọn ti ko ṣe Yahoo lawọn agbofinro mu ti wọn ṣi ahamọ wọn.
Segun salaye pe eyi lawọn ọdọ ri gẹgẹ bi iwa irẹnije ti wọn fi yari mọ awọn agbofinro lọwọ.
Bakan naa, Ọgbẹni Lekan Ọlawale sọ pe awọn ọdọ ilu binu si iwa ilọnilọwọ gba tawọn agbofinro n hu ni ilu naa.
“Awọn agbofinro mu awọn ọdọ ilu ti wọn kìí se ọmọ yahoo, ti awọn obi wọn si n lọ fi owo gba wọn kalẹ lagọ ọlọpaa, nigba to di ọjọ keji wọn tun tun wọn mu pada.
“Eyi lo si bi awọn ọdọ ati awọn obi mi ninu ti wọn fi bẹrẹ ifẹhonuhan lana.”
O fikun kun ọrọ rẹ pe ibi tawọn ọdọ ti wọn jẹ yahoo ti n se fàájì lawọn ọlọpaa ti lọ mu wọn.
“Ti awọn ọdọ si bẹrẹ si ni dana sun taya lana, ti wọn ṣi lọ koju awọn ọlọpaa, lẹyin naa lawọn ọlọpaa lọ mu awọn ọdọ ninu ile lọ kọọkan ati ẹni to kan ati ẹni ti ko lọwọ ninu ọrọ naa.
Lekan Ọlawale salaye pe wọn ti ko awọn ologun wọ ilu Omu-Aran bayii.
O fikun pe oni ọjọ isẹgun lọja ìlu Omu-aran, ṣugbọn wọn o ni naja lọla nitori iṣẹlẹ yii.
O salaye pe bi wọn se bẹrẹ ifẹhonuhan, ni wọn gba aafin kabiyesi ilu naa lọ.
“Ibi ti wọn ti n fẹhonuhan lọwọ lawọn ọlọpaa ti tu wọn ka pẹlu afẹfẹ tajutaju (tear gas).”
“Igba ti agbara awọn ọlọpaa ko fẹ ka wọn mọ lawon osisẹ ajọ eleto abo ara ẹni labo ilu Civil Defence naa kun wọn lọwọ.
Ibẹ naa ni awọn ọmọ ologun ti wọle de, ni ọrọ si di bo lọ, ko yago fun mi.”
O ni se lawọn obirin naa tu jade lọpọ lati darapọ mọ awọn to n fẹhonuhan.
Ninu atẹjade kan eyi ti alaga ẹgbẹ idagbasoke ilu Omu-Aran, Ọgbẹni Niyi Adeyeye fi sita, o rọ awọn araalu naa lati gba alaafia laaye.
Alaga naa ni araalu to ba ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iṣẹlẹ naa, ko fi to awọn leti.
Ninu ọrọ rẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Adetoun sọ pe rogbodiyan naa bẹrẹ lọjọ Sunday ọjọ kẹdọgbọn oṣu yii lasiko ti awọn ọlọpaa lọ mu ogbologbo alagbata ogun oloro ti orukọ rẹ n jẹ Azeez, AKA A Z.
Lasiko ti wọn gbe lọ si agọ ọlọpaa lawọn janduku ọdọ da awọn ọlọpaa lọna, ti wọn si gbe Afunrasi na lọ.
O salaye pe wọn tun lọ dana sun ọkada ọlọpaa to jẹ ẹṣọ alaabo fun Kabiyesi ni aafin.
Adetoun fi kun pe awọn janduku ọdọ yii kan naa lọ kọlu agọ ọlọpaa tawọn ọlọpaa ko si ri iṣẹ ṣe.
Bakan naa lo ni awọn janduku yii kọlu ile ifowopamọ alabde ti Olomu Aperan, wọn ju okuta, wọn si ba CCTV camera jẹ ati awọn ọkọ mẹta to wa ni ile ifowopamọ si naa,
O salaye pe bi awọn ọlọpaa se de sibẹ, ni wọn na papabora, ti awọn ọlọpaa si doola awọn oṣiṣẹ marun ile ifowopamọ si naa.
Adetoun ni ọwọ ti tẹ eeyan marun lori iṣẹlẹ ikọlu naa.
O ni Kọmisona ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo ti pasẹ ki eto aabo tun gbopọn si pẹlu iparaaro awọn ọlọpaa yika igboro ilu naa.
Adetoun ni iwadii si tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa, o wa rọ araalu lati gba alafia laaye ki wọn si fọwọso wọpọ pẹlu ajọ ọlọpaa.