Kò sí iyekíye tó lè mú kí n farahàn nínú ètò Naijiria mọ́ – Doyin

Kò sí iyekíye tó lè mú kí n farahàn nínú ètò Naijiria mọ́ – Doyin

 

 

Irawo Elegbon Agba Naijiria, Doyin David, ti bura pe ko ni bu kun Naijiria pẹlu wiwa rẹ lori ifihan eto eyikeyi mo.

 

Doyin sọ eyi nigba to n salaye awọn iriri rẹ lori ifihan Elegbon Agba Naijiria.

 

Nigba ti o n jiroro lori ipa ti eto naa ni lori igbesi aye rẹ, Doyin sọ pe ikopa oun se akoba fun ilera oun ni opolopo ona.

 

Nigba ti o n fi ẹsun kan awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria pe, oun ṣe akiyesi pe oun ko ni farahan ninu eto Naijiria mo laibikita bi idiyele re yoo se tobi to.

 

Doyin ninu fonran Trendupp Africa to n lo kaakiri, tun sọ siwaju sii pe ẹda ti Ile Elegbon Agba se ṣatunkọ nipa rẹ ti won si fi han awọn oluwo ni won moomo se lati ṣe alaye iru eni to je lona oto lati ni ibaamu pelu itan naa.

 

O ni; “Iriri ti mo ni latari kikopa ninu eto naa jẹ ohun ti ko dara pupọ. Iriri to buru pupọ. Mi o tun ṣe mo laye mi, kii ṣe fun iye eyikeyi, ayafi ti o ba jẹ pe kii se ti orilẹ-ede yi.

 

“Wọ́n ṣe àfihàn rẹ lọ́nà tí wọ́n fẹ́. Wọ́n jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ ohun tí kì í ṣe òtítọ́ nípa rẹ.

 

“Ọpọlọpọ awon eniyan n ro awọn nnkan nipa iwa mi, eyi kii ṣe ẹni ti mo jẹ rara. Ṣugbọn awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria n dani lejọ pupọ, nitori naa mi o tun bu kun wọn pẹlu ifarahan mi mo.”