Àwọn ẹ̀sùn tó wà nínú ìwé ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pe Natasha
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba àpapọ̀ ti sọ pé sẹnetọ tó ń sojú ààrin-gbùngbùn ìpínlẹ̀ Kogi, Natasha Akpoti-Uduaghan lẹjọ, lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ kan tí wọ́n ní ó sọ lórí tẹlifísàn.
Awọn ọrọ naa ni wọn lo sọ tako olori ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ati gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2025 ni ijọba pe ẹjọ naa ni ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja to si darukọ Natasha gẹgẹ bii olujẹjọ.
Ijọba sọ pe Natasha sọrọ to mọ pe o le ba orukọ eeyan jẹ eyii to lodi si abala 391ofin Naijiria ti ijiya rẹ wa ninu abala 392 ofin naa ti wọn gbe kalẹ lọdun 1990.