Ori mi fere daru nigba ti mo gbo pe aisan Lupus wa ni ago ara mi – Kemi Afolabi

Kemi Afolabi

 

… Kemi Afolabi soro lori iriri re pelu aisan Lupus

Mary Seunfunmi Fagbohun

Ilumooka oserebinrin ni, Kemi Afolabi, fi asiri die han nipa bo se fee gba emi ara re n nigba ti o ti n ba aisan Lupus ja laipe sehin.

Gege bi oro re, inira ti oun doju ko po gan-an, ti o si n se laakaye re ni ijamba.

Nigba ti o n so nipa iriri lori aisan na, o wipe:

“Idaniloju ni pe aaraunopolo wa.

E ma se fi edun okan eniyan sere pelu iwa hihu tabi oro siso.

Ori mi fere daru nigba ti mo gbo pe aisan Lupus wa ni ago ara mi, ifoya pelu irewesi okan de bami. Mo korira gbogbo ohun ti mo n la koja.

Mi o ni okun lati se awon nnkan ti mo feran lati se, eyi je ki aanu ara mi semi.

Mi o fi gbogbo nnkan wonyi han fun awon ti mo feran.

O de ibi kan ti mo wa n ri i pe mo n fe se ara mi ni ijamba lopolopo ni. Mo maa n  gbo awon ohun ajeji kan.

Kemi Afolabi: Arokan nii fa ekun asun-un-dake

Mo je oloriire lati se konge awon eniyan nla ti won fi ife ooto han si mi eyi ti o ranmi lowo lati ni idaraya kankan ati wi pe mo dupe nitori emi ti mo n mi ti mo fi san ju eni to ti ku lo.

Leyin naa ni mo se ileri wi pe n o maa gbe pelu oun ti mi o le yipada. Mo wa n gba kadara wipe bi mo se ri re e.

Bi awon eniyan se n se ti nnkan ba waye yio je ki oye aye ye yin.

“Gbogbo eda ni o ni isoro ti won n koju.

Eyi ni lati gba awon eni ti o n la isoro kan koja niyanju lati ma se ropin tabi ni irewesi okan.

“E JOWO E GBA BO SE RI BAYII, KI E SI GBAGBO PE GBOGBO RE YI O YIPADA SI RERE BO PE BO YA.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here