Peter Obi sọ pé kí Ọnanuga tọrọ àforíjì kó sì sanwó ìtanràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́…..

Gbọ́láhàn Quseem

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra nígbà kan rí, tó tún jẹ́ olùdíje dupò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nínú ètò ìdìbò gbogbo-gbòò tó kọjá, Peter Obi, ti kọ̀wé sí Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinubu lórí ẹ̀sùn kan tí Ọ̀gbẹ́ni Bayọ Ọnanuga, fi kàn òun tí kìí ṣòótọ́.

Obi ni ki Ọnanuga tọrọ aforiji lọwọ oun laarin ọjọ mẹta, ko si tun san biliọnu marun-un Naira gẹgẹ bi owo ‘gba, ma binu’ fun ẹsun eke to fi kan oun, aijẹ bẹẹ, oun ati ẹ yo jọ gbe mu nkan ‘lẹ niwaju ni ‘le-ẹjọ

Ẹ o ranti pe lẹnuni lọọlọọ yi ni Ọnanuga fẹsun kan Obi lori ẹrọ ayelujara rẹ pe oun lo wa lẹyin gbogbo wahala tawọn ọmọlẹyin rẹ n dasilẹ, paapaa latari bawọn kan ṣe n leri leka pe awọn yo ṣe iwọde ati ifẹhonu han ta ko ijọba Aarẹ Tinubu.

O ni Peter Obi lo n dana ija naa labẹnu, ohun to si n fọn si fere awọn alatilẹyin rẹ n gbe sita.

Ọnanuga ke sawọn agbofinro gbogbo ninu ọrọ rẹ ọhun pe ki wọn tara ṣaṣa lọọ mu Peter Obi nibikibi to ba wa, o ni ki wọn tete bẹrẹ si fibeere po o nifun pọ, ati pe ti aburu kan ba fi le tidi ifẹhonuhan ọhun jade, Obi lo maa dahun fun-un.

Amọ loju-ẹsẹ ni ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti fesi si ọrọ yi nipasẹ Alukoro wọn, Obiorah Ifoh, pe irọ gbuu ni awọn ẹsun naa, o ni Ọnanuga n sọ ohun t’oju rẹ ko to

Amọ ninu lẹta kan ti Peter Obi kọ si Ọnanuga, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Amofin agba Oloye Alex Ejesieme, o ni ọrọ ibanilorukọjẹ ati ifẹsun eke kan ni gbaa ni ọrọ ọhun ti Ọnanuga sọ nipa onibaara oun jẹ.

Latari eyi, o ni Ọnanuga ni lati san biliọnu marun-un owo itanran fun bo ṣe ta ẹrẹ si aṣọ aala Peter Obi, o si gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ rẹ, o tun ni lati ko ọrọ rẹ jẹ ninu awọn oju-iwe awọn iwe iroyin ilẹ wa meloo kan.

Lẹta naa sọ pe laarin wakati mejilelaadọrin ni ki Ọnanuga ti gbe igbesẹ titọrọ aforiji naa, aijẹ bẹẹ, o ni lati san ṣokoto rẹ kia, ko si mura lati pade awọn nile-ẹjọ, tori awọn ti ṣetan lati wọ tuuru de kootu lori ẹsun ibanilorukọjẹ, ifẹsun eke kan ni ati mimọ-ọn-mọ kan ni labuku to ṣe si Peter Obi.

Ọpọ awọn to sọrọ lori iṣẹlẹ yi ni wọn kan saara si Peter Obi lori igbesẹ to gbe yi. Lori ẹrọ ayelujara, Micheal Nwaechiodo sọ pe, “Inu mi dun pe Peter Obi ṣe ohun to ṣe yii. Ọkunrin ti wọn n pe ni Ọnanuga yi ti fẹ maa koyan ni rira pẹlu awọn ọrọ kọrọ to n jade lẹnu ẹ sigboro aye’’.

Bakan naa ni Aniekan Nelson sọ pe, “Peter Obi fẹ ki Bayọ Ọnanuga mọ pe bo ba debi olufimọ, aa fọrọ mọ ni. Opin gbọdọ de ba iroyin eke nitori oṣelu.”
Bẹẹ lawọn min-in naa sọ.a ipinlẹ Anambra nigba kan rí, tó tún jẹ́ olùdíje dupò ààrrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nínú ètò ìdìbò gbogbogbò tó kọjá, Peter Obi, ti kọ̀wé sí Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinubu lórí ẹ̀sùn kan tí Ọ̀gbẹ́ni Bayọ Ọnanuga, fi kan-an òun tí ki i ṣòoótọ́.

Obi ni ki Ọnanuga tọrọ aforiji lọwọ oun laarin ọjọ mẹta, ko si tun san biliọnu marun-un Naira gẹgẹ bi owo ‘gba, ma binu’ fun ẹsun eke to fi kan oun, aijẹ bẹẹ, oun ati ẹ yo jọ gbe mu nkan ‘lẹ niwaju ni ‘le-ẹjọ

Ẹ o ranti pe lẹnuni lọọlọọ yi ni Ọnanuga fẹsun kan Obi lori ẹrọ ayelujara rẹ pe oun lo wa lẹyin gbogbo wahala tawọn ọmọlẹyin rẹ n dasilẹ, paapaa latari bawọn kan ṣe n leri leka pe awọn yo ṣe iwọde ati ifẹhonu han ta ko ijọba Aarẹ Tinubu.

O ni Peter Obi lo n dana ija naa labẹnu, ohun to si n fọn si fere awọn alatilẹyin rẹ n gbe sita.

Ọnanuga ke sawọn agbofinro gbogbo ninu ọrọ rẹ ọhun pe ki wọn tara ṣaṣa lọọ mu Peter Obi nibikibi to ba wa, o ni ki wọn tete bẹrẹ si fibeere po o nifun pọ, ati pe ti aburu kan ba fi le tidi ifẹhonuhan ọhun jade, Obi lo maa dahun fun-un.

Amọ loju-ẹsẹ ni ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti fesi si ọrọ yi nipasẹ Alukoro wọn, Obiorah Ifoh, pe irọ gbuu ni awọn ẹsun naa, o ni Ọnanuga n sọ ohun t’oju rẹ ko to

Amọ ninu lẹta kan ti Peter Obi kọ si Ọnanuga, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Amofin agba Oloye Alex Ejesieme, o ni ọrọ ibanilorukọjẹ ati ifẹsun eke kan ni gbaa ni ọrọ ọhun ti Ọnanuga sọ nipa onibaara oun jẹ.

Latari eyi, o ni Ọnanuga ni lati san biliọnu marun-un owo itanran fun bo ṣe ta ẹrẹ si aṣọ aala Peter Obi, o si gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ rẹ, o tun ni lati ko ọrọ rẹ jẹ ninu awọn oju-iwe awọn iwe iroyin ilẹ wa meloo kan.

Lẹta naa sọ pe laarin wakati mejilelaadọrin ni ki Ọnanuga ti gbe igbesẹ titọrọ aforiji naa, aijẹ bẹẹ, o ni lati san ṣokoto rẹ kia, ko si mura lati pade awọn nile-ẹjọ, tori awọn ti ṣetan lati wọ tuuru de kootu lori ẹsun ibanilorukọjẹ, ifẹsun eke kan ni ati mimọ-ọn-mọ kan ni labuku to ṣe si Peter Obi.

Ọpọ awọn to sọrọ lori iṣẹlẹ yi ni wọn kan saara si Peter Obi lori igbesẹ to gbe yi. Lori ẹrọ ayelujara, Micheal Nwaechiodo sọ pe, “Inu mi dun pe Peter Obi ṣe ohun to ṣe yii. Ọkunrin ti wọn n pe ni Ọnanuga yi ti fẹ maa koyan ni rira pẹlu awọn ọrọ kọrọ to n jade lẹnu ẹ sigboro aye’’.

Bakan naa ni Aniekan Nelson sọ pe, “Peter Obi fẹ ki Bayọ Ọnanuga mọ pe bo ba debi olufimọ, aa fọrọ mọ ni. Opin gbọdọ de ba iroyin eke nitori oṣelu.”
Bẹẹ lawọn min-in naa sọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here