Ogun láwọn tó ń pè fún ìwọ́de ń fẹ́, a ò fẹ lágbègbè wa – Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀

Ogun láwọn tó ń pè fún ìwọ́de ń fẹ́, a ò fẹ lágbègbè wa – Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní n tó kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sí ẹlòmíìràn.Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ dá bí àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá ti pàrọwà sáwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà láti gbé ẹ̀hónú gba ọ̀nà mìíràn dípò bí wọ́n ṣe ń gbèrò láti ṣe ìwọ́de tako ìjọba tó wà lódé.

Láti bí ọjọ́ mélòó kan ni ìròyìn ti gba orí ayélujára, táwọn ọ̀dọ́ kan sì ń pe ara wọn jọ láti kópa nínú ìwọ́de tí wọ́n pe àkọ́lé rẹ̀ ní “ìlú ò fararọ” láti fi ẹ̀hónú wọn hàn sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ ọdún 2024 ni ìrètí wà pé ìwọ́de náà máa bẹ̀rẹ̀ tó sì máa wáyé fún ọ̀sẹ̀ kan.

Láti ìgbà tí ìkéde náà sì ti ń wáyé ni àwọn èèkan ìlú, ẹgbẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ti ń ṣèkìlọ̀ pé kí àwọn ọ̀dọ́ má ṣe ìwọ́de náà.

Bí ìkìlọ̀ ṣe ń wáyé látọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ káàkiri ni àwọn àgbà ilẹ̀ Yorùbá náà kò dákẹ́, tí wọ́n sì ń sọ pé àwọn kò fẹ ìwọ́de kankan nílẹ̀ Yorùbá.

Nígbà tí àwọn akọroyin kàn sí Baale Ekotedo ti ìlú Ibadan, òlú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo, Olóyè Taye Ayorinde ní ìwọ́de ọ̀tẹ̀ ni àwọn tó ń gbèrò ìwọ́de náà fẹ́ ṣe.

Olóyè Ayorinde ní àwọn tọ ń gbèrò ìwọ́de náà fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ da ojú ìjọba tó wà lóde délẹ̀ ni.

Ó ní ìjọba tó wà lórí ìpò kò ì tíì lo ju ọdún kan lọ àti pé gbogbo ìpèníjà tó ń wáyé kìí ṣe ohun tó jẹ́ pé ìjọba yìí ló dá sílẹ̀.

Ó sọ pé tí kìí bá ṣe wí pé ejò lọ́wọ́ nínú, kò yẹ kí àwọn èèyàn dìde ogun síjọba nítorí ogun ni ìwọ́de náà jọ ní irú àsìkò yìí.

Ó fi kun pé tí àwọn èèyàn bá fẹ́ ṣe ìwọ́de kí oníkálukú lọ sí ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti pé àwọn kò fẹ́ ìwọ́de ní ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀.

Ó ní tí wọ́n bá ṣe ìwọ́de, àwọn ọmọ jàǹdùkú le ti ara bẹ́ẹ̀ gba ìwọ́de náà mọ́ àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n sì máa fi da omi àláfíà ìlú rú.

Ó rọ àwọn ọ̀dọ́ láti gbájúmọ́ iṣẹ́ pàápàá iṣẹ́ àgbẹ̀ dípò lílo àsìkò láti fi ṣe ìwọ́de tí kò ní ṣe àǹfàní kankan fún ìlú.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọ Oodua ní àgbáyé ìyẹn Yoruba Council Worldwide (YCW), Oladotun Hassan sọ pé láti ìgbà tí ààrẹ Tinubu ti wà lórí ipò ló ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ láti fi mú ayé dẹrùn fún gbogbo èèyàn.

Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan ìwúrí ni Tinubu ń ṣe bíi fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láṣẹ láti máa ná owó wọn fúnra wọn àti sísọ owó oṣù tó kéré jùlọ di 70,000 lẹ́nu ìgbà tó di ààrẹ àti pé kò yẹ kó jẹ́ pé wọ́n máa ṣe ìfẹ̀hónúhàn ni.

Hassan ní ó fojú hàn pé ìwọ́de tí wan fẹ́ ṣe náà ní ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú àti pé irúfẹ́ ìwọ́de tó wáyé lọ́dún 2020 ìyẹn Endsars kò bí èso rere.

Ó ní ìdí táwọn àgbà Yorùbá ṣe ń tako ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko kò ṣẹ̀yìn àwọn nǹkan tó tẹ̀yìn ìwọ́de Endsars jáde àti pé ìwọ́de tí àwọn kan ń pè fún lásìkò yìí dàbí wí pé wọ́n ń pè fún ogun ni.

Ó sọ pé Tinubu nìkan kọ́ ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa wọ́ ìdí rẹ̀, ó ní àwọn gómìnà àti ọ̀pọ̀ mínísítà ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ bá sọ̀rọ̀.

Ó fi kun pé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Kenya náà yẹ kó jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà nítorí ìwọ́de náà padà di nǹkan tí ẹ̀mí àwọn èèyàn ń lọ sí.

Ó pàrọwà sáwọn ọ̀dọ́ láti pè fún ìjíròrò pẹ̀lú ààrẹ dípò láti máa gbèrò ìwọ́de.

Bákan náà ló rọ ààrẹ láti pèsè ààyè tí àwọn ọ̀dọ́ fi lè máa rí ààrẹ tàbí aṣojú ààrẹ bá sọ̀rọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ kóówá wọn.

Ó ní kò yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ fàyè sílẹ̀ fún àwọn olóṣèlú láti máa lò wọ́n tako ara wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here