Ọwọ́ àwọn àjọ òṣìṣẹ́ sifudiẹnsi tẹ àwọn afurásí méjì tí wọ́n ṣòwò egbòogi oloró ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Ọwọ́ àwọn àjọ òṣìṣẹ́ sifudiẹnsi tẹ àwọn afurásí méjì tí wọ́n ṣòwò egbòogi oloró ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

lbrahim Adédèjì.

Ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ sífúdìfẹǹsì ẹka tí ìpínlẹ̀ Òǹdó, ti tẹ àwọn afurasí méjì kan tí wọ́n fẹsùn kàn pé wọ́n ń ṣòwò òògùn olóró nílùú Aykurẹ.

Awọn afurasi ọhun, Chukwudi Victor Amoke, ọmọ bibi ijọba ibilẹ Igboeze, nipinlẹ Enugu, ati ọrẹ rẹ, Timilẹyin Abed, to wa lati Ilogbo Ekiti, lọwọ tẹ nitosi ileetura kan ti wọn n pe ni Benue, eyi to wa lagbegbe Ṣáṣá, Ọba-Ile, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro sifu difẹnsi tipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Daniel Aidamembor, fi ṣọwọ si awọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje yii, o ni iṣẹ ti Chukwudi ati ẹni keji rẹ yan laayo ju lọ ni pinpin ati tita oriṣiiriṣii oogun oloro fawọn onibaara wọn niluu Akurẹ ati agbegbe rẹ.

Aidamembor ni agbegbe Zone A Glory Land, l’Akurẹ, ni Chukwudi fi ṣe ibugbe, nigba ti Timilẹyin to jẹ ọrẹ rẹ n gbe l’Ojule kẹrinlelogun ninu ọja Ṣaṣa, niluu Akurẹ, kan naa.

Yatọ si ọkan-o-jọkan oogun oloro to ni awọn ba nikaawọ wọn, awọn afurasi mejeeji lo ni wọn tun jẹwọ lasiko ti awọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo pe loootọ lawọn n ṣowo egboogi oloro.

O ni awọn ti n gbe igbeṣẹ lati fi awọn mejeeji ṣọwọ sọdọ ajọ to n gbogun ti oogun oloro lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ọrọ wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here