Ẹ gbọ! Wọ́n ní Tinubu lọ́wọ́ nínú wàhálà oyè Emir nílùú Kano

Ẹ gbọ! Wọ́n ní Tinubu lọ́wọ́ nínú wàhálà oyè Emir nílùú Kano

Gbọ́láhàn Quseem
À fi kí Ọlọ́run má jẹ́ kí wọ́n parọ́ tó jọni mọ́ni.
Ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ní ìpínlẹ̀ Kano, Hashimu Dungurawa, ti fẹsùn kan Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé òun ló ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín Muhammadu Sanusi Kejì àti Aminu Ado Bayero ní ìpínlẹ̀ Kano.

Ọjọgbọn Hashimu ló sọ ọ̀rọ̀ náà nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú àwọn akọròyìn níbi tó ti sọ pé òun ni ẹrí ti kò se é takò láti fi kín ọ̀rọ̀ òun lẹ́yìn.

O ni “O han gbagba pe Aarẹ Tinubu lọwọ ninu ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ laarin àwọn
mejeeji.

“Tinubu, latari ibaṣepọ rẹ pẹlu iya to bi Emir ana, iyẹn Aminu Ado Bayero, sọ pe oun ko ni gba ayafi ti wọn ba da pada sipo to wa tẹlẹ.

“Wọn ko awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun wa s’ilu Kano lasiko naa ti Naijiria n koju iṣoro eto abo, eyii ko si ṣẹyin erongba rẹ lati gbogun ti awọn ti ko ṣatilẹyin fun.”

Nigba ti awọn akọroyin bere lọwọ adari ẹgbẹ NNPP naa boya o ni ẹri lati kin ọrọ rẹ lẹyin, o ni “Ta ni Aarẹ Naijiria lọwọ yii? Ṣe ki n ṣe Tinubu ni? Njẹ o ṣeeṣe ki wọn ko ọlọpaa ati ọmọ ogun lọ si agbegbe kan fun ọpọlọpọ oṣu ki Aarẹ ma mọ nipa rẹ? To ba sọ pe oun ko mọ, a jẹ pe wahala wa nigbayẹn.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here