Ìjọba àpapọ̀ yẹ kó fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kàn láyè àti ṣàkóso ohun àlùmọ́ọ̀nì wọn– àgbàríjọ gómìnà ilẹ̀ Yorùbá

Ìjọba àpapọ̀ yẹ kó fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kàn láyè àti ṣàkóso ohun àlùmọ́ọ̀nì wọn– àgbàríjọ gómìnà ilẹ̀ Yorùbá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àfẹnukò àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ti rọ ìjọba orílẹ̀èdè yìí pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe àgbéyẹ̀wò bí owó ṣe n wọlé ní ìpínlẹ̀ kálùkù wọn, kí wọ́n fi sètò àfikún owó-oṣù táwọn òṣìṣẹ́ n bèèrè fún lọ́wọ́ ìjọba báyìí. Wọ́n ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ níye owó àti iṣẹ́ ìdàgbàsókè táwọn gómìnà ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan n ṣe láàrin ìlú wọn, fún ìdí èyí, ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ló mọ bówó ṣe n wọlé sápò rẹ̀ àti bó ṣe lágbara tó láti ṣe àfikún sí owó oṣù táwọn òṣìṣẹ́ orílẹ̀èdè yìí n bèèrè fún báyìí.

Nibi ipade pataki kan to waye laarin awọn ọmọ ẹgbe naa niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn ti fẹnu ko laarin ara wọn, ti wọn si sọ erongba wọn sita l’Ọjọbọ, ọsẹ yii.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori ipinu wọn ni wọn ti rọ ijọba orileede yii pe ki wọn faaye gba ipinlẹ kọọkan lati maa ṣakooso ohun alumọọni to wa niluu kaluku wọn, ki idagbasoke ati ilọsiwaju le tete de ba wọn.

Wọn ni ki i ṣohun to daa rara bijọba yii ṣe n fawọn oniṣowo niwee lati maa wa kusa tabi ohun alumọọni nipinlẹ kan lai jẹ pe awọn gomina ibẹ mọ si i. Fun apẹẹrẹ, wọn ni akoba nla ni iru igbesẹ bẹẹ maa n fa laarin ilu.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here