N30bn la bá ní báńkì méjì tó jẹ́ ti Mompha, nílànà jìbìtì wíwọ́ ike – EFCC

N30bn la bá ní báńkì méjì tó jẹ́ ti Mompha, nílànà jìbìtì wíwọ́ ike – EFCC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kánjúà ń dàgbà,ọgbọ́n inú ẹ̀ ń rewájú
Àjọ tó n rí sí àjẹbánu lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti tako ọkùnrin jayéjayé tó gbajúmọ̀ lórí ayélujára nnì, Ismaila Mustapha táwọn èèyàn mọ̀ sí Mompha, lórí owó rẹpẹtẹ tí wọ́n tọpinpin dé àpò ìkówópamọ́ síi rẹ̀ ní báńkì.

Atọpinpin kan to jẹ oṣiṣẹ lọdọ ajọ EFCC, Idi Musa, jẹri tako Mompha ni kootu lọjọ Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu keje ọdun 2024 yii, nigba to ni oun tọpinpin biliọnu lọna ọgbọn si akanti ọmọ jayejaye ọhun.

Mompha, ẹni ti wọn ṣi n wa titi di asiko yii ni wọn lo ni ileeṣẹ kan torukọ rẹ n jẹ Ismalob Global Investment Ltd.

Mompha ati ileeṣẹ rẹ ni EFCC pe lẹjọ, lori ẹsun ṣiṣe okoowo to lodi sofin, ṣugbọn ti wọn n fi nnkan mi-in boju bii iṣẹ gidi ti wọn n ṣe lati ri owo. (Money laundering).

EFCC ni oun ti ri owo nla to wa ninu asunwọn Mompha ni banki Fidelity ati Zenith to n lo.

Ẹlẹrii EFCC to tako Mompha, ṣalaye pe ninu itọpinpin loun ti ri aṣiri Mompha ati ileeṣẹ rẹ .

Idi Musa tẹsiwaju ninu atako naa pe ni 2019, ẹka ijọba apapọ to n wadii (FBI), ta EFCC lolobo nipa jibiti ori ayelujara ti Mompha ati ileeṣẹ rẹ lu awọn eeyan lorilẹde Amẹrika.

Ó fi kún un pé láàrin Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè òkè òkun ni Mompha àti iléeṣẹ́ rẹ̀ ti n ‘wọ́ke’, tí wọ́n n lu àwọn èèyàn ní jìbiìtì lórí ayélujára.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here