Yilwatda di alága e̩gbé̩ òsèlú APC
Yínká Àlàbí
O̩jo̩gbo̩n Nentawe Yilwatda di alaga agba e̩gbe̩ oselu APC.
Ipade oni ni ipade ako̩ko̩ ti awo̩n e̩gbe̩ agba oselu APC maa se le̩yin iku Aare̩ ana, Muhammadu Buhari. Le̩yin idide ise̩ju kan fun Aare̩ ana ni alaga awo̩n gomina fun e̩gbe̩ oselu APC, Alagba Hope Uzodinma tii se gomina ipinle̩ Imo kede alaga naa. Ipinle̩ Plateau ni o ti wa.