Yekini Adeojo, àgbà òṣèlú jáde láyé, Makinde àtàwọn èèkàn ìlú ń dárò ikú rẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwáyé è kú ò sí,èrò ọkọ̀ lásán ni gbogbo wa láyé, ibùsọ̀ tí a tí ń bọ́ sílẹ̀ ló yàtọ̀ síra wọn .
Olóyè Yekini Adeojo, Ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú ńlá nílùú Ìbàdàn àti ní Nàìjíríà lápapọ̀ ti jáde láyé.
Aarọ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin ọdun 2025 lo papoda.
Oloogbe Yekini Adeojo jẹ ọkan lara awọn to da ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ nipinlẹ Oyo.
O ti figba kan ri jẹ Igbakeji Alaga apapọ ninu ẹgbẹ PDP ni ẹkun Guusu.
Bakan naa lo si tun jẹ oye nla ti i ṣe Seriki Musulumi.
Oloye pataki ni Yekini Adeojo ṣaaju iku rẹ niluu Ibadan.
Oloogbe Adeojo ni baba to bi Ọnarebu Sheriff Aderemi Adeojo, Alaga ijọba ibilẹ Ido, lọwọlọwọ
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, wa lara awọn eeyan to ti n ba idile Adeojo kedun iku naa.
Makinde ṣapejuwe Oloogbe Adeojo bii ẹnikan ṣoṣo to ṣẹku ninu awọn agba asiko rẹ.
O ni iku rẹ fopin si asiko oṣelu ologo igba naa ni.
Gomina rọ awọn ẹbi Adeojo lati ṣe ọkan giri lori iku Oloogbe Yekini Adeojo, ẹni to du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP ni 1999.
O gba a ladura pe Ọlọrun yoo fun wọn lagbara lati gba ohun to ṣẹlẹ yii.
Bẹẹ ni Makinde ba gbogbo PDP ipinlẹ Oyo naa kẹdun ara fẹrraku Oloye Yekini Adeojo.
Oloye pataki ni Oloogbe Yekini Adeojo n’Ibadan, bẹẹ naa lo si tun jẹ oloṣelu.
Ọpọ igba lo ti gbiyanju lati di gomina ipinlẹ Oyo, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe.
Ohun to n fa eyi nigba naa gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ni pe aarin Adeojo ati Oloogbe Lamidi Adedibu ko gun.
Eyi ko si jẹ ki ipo naa ja mọ Adeojo lọwọ bo ṣe gbiyanju to.
Bi Oloogbe Yekini Adeojo ṣe jẹ oloṣelu lo tun jẹ agba ninu ẹsin Islam.
Musulumi ododo to maa n pe fun alaafia ati iṣokan ni. Bakan naa lo si tun maa n kede pe ẹsin o faja.
