Wọ́n sọ fún ìyá mi láti jù mí nù ní kékeré nítorí mo ní àìsàn ‘Sickle Cell’ – Olopade Popoo̩la

Wọ́n sọ fún ìyá mi láti jù mí nù ní kékeré nítorí mo ní àìsàn ‘Sickle Cell’ – Olopade Popoo̩la

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́ pé àwọn tí wọ́n bá ti ní àìsàn Sickle Cell kìí pẹ́ kú nítorí bí àìsàn náà ṣe máa ń dáwọn gúnlẹ̀ ní gbogbo ìgbà.

Àmọ́ èyí ti ń yípadà nítorí lóde òní àwọn tó ní àìsàn ti ń lé ní ọgọ́ta ọdún láyé.

Èyí ló bí ìròyìn yìí nípa arábìnrin yìí tó ti lé ní ọgọ́ta ọdún láyé lẹ́yìn tó ti ní ìpèníjà àìsàn sickle cell lati ìgba tí wọ́n ti bii, tí àwọn ènìyàn sì sọ fún ìyá rẹ̀ pé kí ó lọ sọ́nù.

Abílékọ Modupe Olopade Popoola ṣàlàyé àwọn ìlàkàkà tó dojúkọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní àìsàn Sickle Cell nígbà tó ń dàgbà.

Modupe ní ìgbà tí òun wà ní ọmọ oṣù márùn-ún ni ìyá mọ̀ wí pé òun ní àìsàn náà tí àwọn ènìyàn sì sọ fún ìyá òun pé kó lọ sọ òun nù nítorí àwọn ọmọ tó bá ní àìsàn náà kìí yè é.

Ó ní màmá òun ní òun kò ní sọ ọmọ òun nù àti pé Ọlọ́run tó fún òun ma bá òun wo ọmọ náà.

Ó fi kun pé àwọn ọmọ kíláàsì òun máa ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí òun wà ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nítorí òun kìí lọ sílé ẹ̀kọ́ dédé tí àìsàn náà bá ti dá òun gúnlẹ̀.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni òun máa ń gba ẹ̀jẹ̀ tí òun máa ń wà ní ilé ìwòsàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ àti pé àwọn ìnìra tí òun máa ń kojú nígbà náà kò kéré rárá.

Modupe ní àwọn dókítà sọ fún ìyá òun pé ó ṣeéṣe kí òun má pè é ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún láyé àmọ́ pẹ̀lú ògo Ọlọ́run òun ti lé ní ọgọ́ta ọdún láyé báyìí.

Ó tẹ̀síwájú pé mímóríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn sickle cell kìí ṣe òun tó wáyé pẹ̀lú ìrọ̀rùn nítorí onírúurú ìṣòro àti ìpèníjà ni òun là kọjá kí òun tó dàgbà tó bí òun ṣe wà lónìí.

Ó ní wọ́n lé òun kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ kan nítorí òun lọ sílé ìwòsàn olùkọ́ni tó wà ní Ibadan fún ìtọ́jú ara òun.

Ó fi kun pé àìsàn náà ti kọ́ òun ní àwọn nǹkan tó yẹ láti gbé ìgbé ayé tó rọrùn nítorí gbogbo àwọn ìnìra tí òun ti là kọjá náà ni òun di ọkàn òun.

Ó ní ìdí nìyí tí òun fi ń ró àwọn ọmọ tó ní ìpèníjà bíi ti òun lágbára láti lè jẹ́ kí àwọn náà wúlò fún àwùjọ wọn.

Ìyá Modupe, Henrienta Olopade ní láti ìgbà tí òun ti mọ́ pé ọmọ òun ní ìpèníjà àìsàn yìí ni òun kìí jẹ́ ki ẹsẹ̀ òun já nílé ìwòsàn UCH Ibadan.

Henrienta ní kété tí òun bá ti rí pé ara rẹ̀ gbóná díẹ̀ ni òun máa mórílé ilé ìwòsàn àti pé nínú gbogbo ọmọ tí òun bí Modupe nìkan ló ní ìpèníjà àìsàn náà.

Ọmọ tó bá ní Sickle Cell kìí lò ju ogun ọdún lọ láyé?

Olùdásílẹ̀ àjọ Sickle Cell Foundation of Nigeria, Annette Akinsete ní àròsọ lásán ni ọ̀rọ̀ náà nítorí pẹ̀lú ìmójútó tó dára, àwọn tó bá ní àìsàn yìí le pẹ́ láyá dáradára.

Ó ní àwọn tó ní Sickle Cell tó ti lé ní ọgọ́ta sí ọgọ́rin ọdún láyé wà ní àjọ àwọn tí wọ́n sì ń ṣe dáadáa.

Annette ní àmójútó tó péye àtàwọn ìtọ́jú tó dára ni àwọn tó ní àìsàn yìí níl]o jùlọ.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó ní àìsàn yìí ni wọ́n máa ń ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà ní agbègbè kóówá wọn.

Bákan náà ló kọminú pé àwọn ọmọdé tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ló máa ń pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn sickle cell ní Nàìjíríà ní ọdọọdún.

Ó fi kun pé ìpolongo lórí àmòjútó sickle cell gbọ́dọ̀ rí ìrúgọ́gọ́ ju bó ṣe wà báyìí lọ.