Wọ́n bí mi lọ́dún 1944, mo di Olúbàdàn 44th, àànú Ọlọ́run ni- Ládojà

Wọ́n bí mi lọ́dún 1944, mo di Olúbàdàn 44th, àànú Ọlọ́run ni- Ládojà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní orí tí yóò bá dádé , lèjìgbà ìlẹ̀kẹ̀ , òhun ìbàdí tí yóò lo ẹ́ẹ̀ mọ́sàjì asọ ọba tí í taná yanranyanran, inú agogo idẹ ní tí i wá. Èyí ló díá fún Olúbàdàn tuntun fún ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Rashidi Adéwọ̀lú Ládọjà bó ṣe gùnlẹ̀ sí ìlú Ìbàdàn láti wá bẹ̀rẹ̀ ètò ayẹyẹ ìfinijoyè rẹ̀ .

Ladoja ni oye Olubadan kàn, lẹyin ti ọba Owolabi Olakuleyin waja.

Ọjọ Mọkalelogun si ni wọn kede lati fi kẹdun iku Olubadan to gbesẹ naa, laarin awọn ọjọ yii naa si ni wọn sinku rẹ nile ijọsin Peteru Mimọ, Aremọ nilu Ibadan.

Ni gbogbo asiko ikẹdun iku ọba to waja naa, ẹni ti ipo ọba kan, tii se Ọtun Olubadan, ko si nile, to si wa nilu Eko.

Amọ ni ana ọjọ Aje ni Olubadan tuntun naa fi tilu tifọn wọle silẹ Ibadan, tawọn araalu si fi tilu tifọn ki kaabọ.
Ni kete to de ẹnu iloro masọsẹ Eko si ilu Ibadan, ni ọpọ ero ti duro lati ki Adewolu kaabọ silu baba rẹ, ti wọn si to lọwọọwọ tẹle mọto rẹ lẹyin.

Agboole Baba rẹ to wa ni adugbo Born Photo ni Isalẹ Osi ni Ladoja morile, lati ki gbogbo ẹbi rẹ ku ile o.

Bo si se n wọ adugbo naa ni awọn eeyan n tu jade lati se ayẹsi rẹ, wọn n jo, wọn n yọ pe oye Olubadan naa ko sile awọn koro.

Awọn onilu gan fi gọngọ dabira si ara ilu pẹlu oniruuru orin ọpẹ.

Lẹyin isẹju diẹ, ni Ladoja kuro ni agboole baba rẹ naa, to si morile ile tiẹ gan to n gbe ni adugbo Bodija atijọ nilu Ibadan.

Koda, awọn ero to n duro de Ladoja nile rẹ naa kọ sisọ, ti isọri orin ọpẹ miran si tun gba ẹnu wọn kan bi wọn se foju ganni Olubadan tuntun naa.

Lẹyin ti Ladoja joko sinu ile tan, lo ba awọn akọroyin to wa nikalẹ sọrọ .