Wó̩n ní Gómìnà Ademola Adeleke ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú PDP

Won ni Gomina Ademola Adeleke ti kúrò nínú ẹgbẹ́ oselu PDP

Mary Fágbohùn

Ayipada oriṣiiriṣii lo n waye lagbo oṣelu Naijiria bayii, pẹlu bi awọn ẹgbẹ oṣelu tuntun ṣe n dide ni igbaradi fun idibo ọdun 2027.

Pẹlu bi awọn oloṣelu Naijiria ṣe n kuro ninu ẹgbẹ kan bọ si ikeji bayii, àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wá ń fi ẹnu kún Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, pé òun náà ti là ìtàn láti kúrò nínú ẹgbẹ́ oselu PDP lọ sí APC.

Kódà, àwọn kan ni imọlẹ tí fẹ́ wọ inú òkùnkùn lọ ní ìpínlẹ̀ Osun èyí tó túmọ̀ sí pé gomina Adeleke, tí ọ̀pọ̀ mọ si Imọlẹ fẹ lọ sí ibòmíràn.

Pẹlu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe wa mú ariwo rẹ bọnu pe o fẹ kúrò ninu ẹgbẹ kan bọ si ikeji bayii, Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti sọ bo ṣe n lọ ni iha tirẹ.

Ninu alaye to ṣe si oju opo X rẹ lọjọ Abameta, ọjọ karun-un, oṣu Keje ọdun 2025, Adeleke tawọn eeyan tun mọ si Imọlẹ, kede pe oun ṣi duro digbi ninu jije oloootọ si ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Osun.

Gomina ipinlẹ Osun naa sọ pe ọmọ ẹgbẹ PDP ṣi loun tọkan-tọkan

”Opolopo ipe ni mo ti n gba lati nnkan bii wakati diẹ sẹyin, ti wọn n beere lọwọ boya mo ti kuro ninu egbe oselu PDP loootọ.

“Mo fẹẹ fi da ẹyin omoluabi ni ipinlẹ Osun loju, pe olootọ ọmọ ẹgbẹ PDP ṣi ni mi. Ko si giri kankan,” Gomina Adeleke lo kede bẹẹ.

O ni afojusun oun ko yipada, ati pe ohun to jẹ oun logun ni ona lati mu awọn ileri oun fun awọn eeyan Osun ṣẹ.

Adeleke fi kun un pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba aheṣo oro to n lọ kaakiri ilu pe oun ti kuro ninu egbe PDP gbọ. O ni ki wọn maa ṣatilẹyin fun ijọba oun lọ