Wèrè l’O̩ló̩run lò fún mi – Sam Olu Alo̩
Okan ninu awon gbajugbaja iranse Olorun ni Wolii Sam Olu Alo, bee lo si tun je okan ninu awon iranse Olorun ti won ri aanu ati oju rere Olorun gba. Laipe yii ni won ba awon oniroyin soro nipa iriri won, paapaa ohun toju ri ki Olorun too tu won sile ninu igbekun ayeraye ati bi Olorun se gbe won pade Ayo Babalola ko too di pe won bere ise iranse. Die lara ohun ti won so ree.
“Emi funra mi mo pe omo ologo ni mi, sugbon mi o ri ogo yii lo nibere pepe aye mi. Ojo kan lemi funra mi, lai je pe enikan so fun mi, pinnu lati fi ilu abinibi mi sile, mo si ba ara mi da majemu pe o digba ti nnkan ba too yipada fun mi ki n too le pada siluu ohun.
“Egbon mi kan to n sise birikila ni mo gba odo won lo, mo bere si i tele won, sugbon won je ki n mo pe awon ko nile tawon le gba mi si, emi naa si so fun won pe mi o setan ati fi won sile, bi won ko tile ni yara ti won maa gba mi si. Mo saa pinnu pe, abule yii o, emi o ni pada sibe mo, digba ti n ba too soriire.
“Ohun akoko ti mo sakiyesi ni pe oga mi, ti won tun je egbon mi yii, kii sise bi awon birikila egbe won yooku. Mo tun sakiyesi pe oye ise naa ye won daadaa. Ileejosin Anglican ni won n lo, emi naa si darapo mo won, mo bere si i ba won josin nibe.
“Gbogbo igba yen ni mo ti n gbo ohun kan to n ko si mi pe; ‘Olorun ni mi i fi se, Olorun fee lo mi’, sugbon mi o gba ohun naa gbo rara, mo ti gba pe mi o le di iranse Olorun laelae, bi mo se maa dolowo, ti mo maa di gbajumo nla ni mo n ro. Ohun to maa n wa si mi lokan nipa ise iranse ni pe ki Olorun bukun fun mi ki n rowo toju awon iranse Olorun. Nitori loju temi, awon iranse Olorun n jiya, sibe emi naa ko lowo kan lowo.”
Baba Adamimogo to tun je oludasile ileejosin Christ Apostolic Church Grace of Mercy Prayer Mountain International tun salaye fun awon akoroyin pe; “Lojo kan ni mo pade okunrin were kan, bo ti ri mi lo so pe; ‘Iwo okunrin yii, Olorun n pe e, o n sise birikila, bo tie je pe anfaani ati kawe ko si fun e, Olorun n pe e, o ko etiikun, oko iparun lo n lo yen o.” Ohun ti okunrin were naa so fun mi lojo naa niyen.
Ki wa ni nnkan to sele gan-an?
“Leyin ti mo pari ekose owo birikila ti mo ko lowo oga mi, egbon mi yii, ojo to ye ki n kuro lodo oga mi gan an ni won le mi jade nile tibinu-tibinu, bee ko si ibi ti mo le lo tabi duro si paapaa, se e ranti pe mo ti pinnu lati ma pada sile.”
Okunrin ojise Olorun yii tun ni, “Leyin ti mo pade okunrin were yii, ni mo wa gba imisi loru ojo kan, mo ri Aposteli Ayo Babalola, bo tie je pe mi o pade won ri loju aye, sugbon mo pade won loju iran, won si n so fun mi loju oorun naa pe Jesu lo n pe mi sise, won ni okunrin ti mo ri bii were loju aye to n ba mi soro yen kii se were rara, won ni Jesu lo n pe mi lati gba ise re.”
Baba yii ni leyin toun ji loju oorun naa, oun ko ri baba to n soro naa mo. “Se lo da bii pe enikan n soro si mi leti, mi o le fi taratara pe e ni iran. Ojo kan gan an ni ile aye mi bere si i gba otun, iyipada de paapaa pelu ebun imo ti Olorun fi fun mi. Leyin naa ni okan mi bere si i fa sodo Olorun, sugbon sibe mo pinnu pe mi o ni sise iranse.
“Mo tun sun, ni mo ba ri i ti won gbe bibeli le mi lowo, mo ka bibeli naa, latigba ti mo si ti ta ji ni mo ti bere si i ka bibeli.”
Wolii Sam Olu Alo ko gbagbe ibi to ti n bo, bo ti n ran won lowo bee lo n saanu fun awon ti won ba iranlowo wa sodo re, paapaa nipase ajo to da sile eyi to ti mu iyipada de ba opolopo awon eeyan lai fi tesin se.
Ni bayii, okunrin naa ti n gbaradi lati gbalejo ipago kan ninu osu kejo yii, nibi ti won ti n reti opo eeyan nibi ipade ohun. Ibudo ipago re ti won pe ni Jesus City Camp ground to wa l’Ekoo nipade ohun yoo ti waye.