WASSCE 2025: Ìdá méjìdínlógójì nínú ọgọ́rùn ún(38%) péré ló yege èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìsirò
Yínká Àlàbí
Ajọ WAEC (West Africa Examination Council) to n se kokari eto idanwo asekagba awọn akẹkọọ oniwe mẹwaa WASSCE (West African Senior School Certificate Examination) ti gbe esi idanwo wọn jade. Wọn ni o maa di wiwo lati ọjọ karun un osu kẹjọ ọdun yii.
Akẹkọọ bii Miliọnu meji lo se idanwo naa laarin osu kẹrin si ikeje kaakiri ile iwe bii ẹgbẹrun mẹrinlelogun. Ọgbẹni Amos Dangut to jẹ ọga WAEC ni Naijiria salaye pe ida mẹtadinlaadọrun un ninu ọgọrun un (87%) lo yege isẹ marun un ti ko pan dandan ki ede Gẹẹsi ati Isiro wa nibẹ. O ni ida mejidinlogoji (38%) lo yege isẹ marun un to ni ede Gẹẹsi ati Isiro ni eyi to ja wale ju ti ọdun to kọja lọ. Ọga agba yii ni ida mejilelaadọrin (72%) ninu ọgọrun un lo ni isẹ marun un pẹlu ede Gẹẹsi ati Isiro lọdun to kọja.
Ọgbẹni Dangut ni ida aadọta din diẹ (49.60%) ni awọn ọkunrin nigba ti ida aadọta le diẹ (50.40%) jẹ ida obinrin to se idanwo naa. Ọga yii ni awọn akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun mejila ni wọn jẹ akanda eniyan ti awọn se idanwo naa fun gẹgẹ bii ipenija ẹnikọọkan wọn. Bẹẹ si ni o tun fi kun un pe ẹlẹgbẹẹ ida mẹtalelogun (22.94%) ni wọn ko le ri gbogbo isẹ wọn wo nitori awọn idi kan tabi omiran ti awọn si n se isẹ lori rẹ lọwọ.