WAEC ṣàlàyé ìdí tó fi ti ojú òpó àyẹ̀wò èsì ìdánwò

WAEC ṣàlàyé ìdí tó fi ti ojú òpó àyẹ̀wò èsì ìdánwò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlàyé.
Àjọ WAEC ti kéde pé àwọn ti bẹrẹ ìwádìí sí ìṣẹlẹ tó ṣẹlẹ̀ sí ojú òpó ayélujára wọn èyí tí kò fún àwọn akẹkọọ ní ànfààní láti yẹ èsì ìdánwò wọn wò.

Atẹjade yii lo jade loju opo ayelujara X ni WAEC ti ni awọn ṣawari awọn kudiẹkudiẹ kan ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati wa ojutu si.

Igbesẹ yii jẹyọ lẹyin ti awọn akẹkọọ to kopa ninu idanwo WAEC ke gbajari sita pe awọn ko ni anfani lati yẹ si idanwo wọn wo.
Nitori iwadii yii ni WAEC fi sọ kọkọrọ si ẹnu ọna abawọle oju opo naa fun igba diẹ, eyi ti yoo fun wọn akoko lati wa ojutu si iṣoro ti wọn n koju.

WAEC ni lẹyin igbesẹ yii, awọn akẹkọọ yoo ni anfani lati yẹ esi idanwo wọn wo lẹyin wakati mẹrinlelogun.
Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2025 ni WAEC kede pe esi idanwo ọhun ti jade sita.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni ajọ WAEC to n ri si idanwo oniwee mẹwaa, fi esi idanwo naa fun ti ọdun yii lede.

Esi idanwo 2025 yii ko fi bẹẹ mu ayọ wa fun ọpọ akẹkọọ to ṣe e ati awọn obi wọn.

Koda, bi a ba fi esi WAEC ọdun 2025 yii we awọn eyi to ti n jade lati ọdun marun-un sẹyin, eyi lo buru julọ.
Akẹkọọ 1,973,365 lo fi orukọ silẹ fun idanwo WAEC ọdun 2025, wọn wa lati awọn ileewe girama ti ijọba fi ọwọ si ni Naijiria, ti onka wọn si jẹ 23,554.

Ṣugbọn akẹkọọ 1,969,313 lo pada jokoo ṣe idanwo naa, gẹgẹ bi ajọ WAEC ṣe sọ.

Onka awọn akẹkọọ ọkunrin to ṣe WAEC ọdun yii bi wọn ṣe wi jẹ 976,787, nigba ti awọn obinrin jẹ 992,526 .

Awọn to yege pẹlu iṣiro ati ede oyinbo ati awọn iṣẹ mẹta mi-in to fi jẹ marun-un, jẹ 754,545.

Ida 38.32% ni eyi si jẹ ninu onka ọgọrun-un.

Ọga Agba ajọ WAEC ni Naijiria, Amos Dangut, sọ pe awọn to yege ninu idanwo ọdun yii dinku ni ida 33.8, ti a ba fi we 72.12 to wọn ri ni 2024.

O ni awọn esi idanwo ida 22.94 kan ṣi wa tawọn n ṣiṣẹ le lori lọwọ.
Nigba to n ṣalaye nipa magomago to ṣee ṣe ko waye ninu idanwo WAEC ọdun yii, Amos Dangut sọ pe esi idanwo 192,089 ni ajọ naa ko ti i gbe jade latari magomago.

Ọga agba WAEC ni Naijiria naa sọ pe ida 9.75% ni eyi ninu awọn akẹkọọ to ṣe idanwo naa lọdun yii.

Dangut ṣo pe adinku ba onka yii ni ida 2.17, ti a ba fi we 11.92% magomago ti wọn ṣe akọsilẹ rẹ ninu idanwo 2024.
Ni 2020, ida 65.24% lo yege idanwo naa pẹlu ede oyinbo ati iṣiro, gẹgẹ bi WAEC ṣe wi.

Ni 2021, o tun pọ si i. Awọn 81.7% lo yege awọn idanwo naa pẹlu iṣiro ati ede oyinbo.

Ni 2022, o dinku si ida 76.36% .

Ni 2023, ida 79.81% lo yege iṣiro ati ede oyinbo pẹlu awọn iṣẹ mi-in.

Adinku tun ba onka naa ni 2024, o ja si 72.12.

Ṣugbọn ni 2025 yii, o ja pata walẹ si 33.8%.
Ninu alaye to ṣe nipa idi ti awọn akẹkọọ fi fidi rẹmi bẹẹ ni WAEC ọdun 2025, olukọ agba kan ni Naijiria, Ọmọwe Harmony Mark-Ewa, ṣalaye fun akọroyin, pe ajọṣepọ to wa laarin ile ati ileewe kere ni.

Ọmọwe Harmony sọ pe iwoye oun ni pe:

“Ibaraẹnisọrọ laaarin ile ti awọn ọmọ ti wa, pẹlu ileewe ti wọn n lọ ko kun to, eyi si n ṣe akoba fun aṣeyori ẹkọ.

O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn obi ki i ṣe afikun ẹkọ ti awọn olukọ n kọ awọn ọmọ naa nile ẹkọ, o si le jẹ pe ti ile ni awọn olukọ ko ṣiṣẹ tọ.

Nipa ẹkọ ile, Mark-Ewa sọ pe ile ni ẹkọ ti bẹrẹ.O ni afikun ni ti ileewe.

Bakan naa lo ni ẹkọ wa nileewe naa, ti wọn yoo sọ di odidi bi wọn ba pada dele.

Ọmọwe Mark-Ewa fi kun un pe awọn obi mi-in maa n ran ọmọ niṣẹ ju, ti ọmọ naa ko si ni i raye lati kawe.

O ni ileewe ti wọn ti kuro ati ile ti wọn n pada si ko jọra wọn, eyi naa le fa ifasẹyin bo ṣe sọ.

Bi awọn akẹkọọ yoo ba bẹrẹ si i ṣe daadaa, Ọmọwe Mark-Ewa sọ pe ajọṣepọ gbọdọ wa laaarin awọn olukọ ati awọn obi.
Lọ si oju opo www. waecdirect.org .

O maa nilo kaadi WAEC ti wa a bo oju rẹ lati wọle soju opo naa.

Lọ si ẹka ti esi naa wa, ti i ṣe www.waecdirect.org.

Fi nọmba idanwo WAEC rẹ si i.

Mu iru idanwo ti o ṣe, fun apẹẹrẹ, ti May/June.

Mu ọdun ti o ṣe idanwo naa, fun apẹẹrẹ 2025.

Tẹ ẹ si ibi ti wọn kọ esi naa si, yoo gbe e jade fun ọ.