UK yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ọ̀daràn ránṣẹ́ sí orílẹ̀èdè won

UK yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ọ̀daràn ránṣẹ́ sí orílẹ̀èdè won

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìdálùú ni ìṣèlú,
ìgbésẹ̀ tuntun kan ti wà nínú ètò tí orílè-èdè UK fẹ́ gbé báyìí, èyí sì ni fífi àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá ti dájọ́ fún lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ránṣẹ́ padà sí orílè-èdè àbínibí wọn.

Akọwe eto idajọ UK lo fidi eyi mulẹ.

Labẹ eto yii ti wọn ṣe fun England ati Wales, awọn ti ẹwọn wọn ba ni gbedeke igba ti wọn yoo lo, le ba ara wọn lorilẹede wọn lẹyẹ o sọka, wọn yoo si tun fi ofin de won lati ma wọ UK mọ laye.

Boya wọn yoo waa tẹsiwaju ninu ẹwọn naa niluu wọn o, tabi ijọba ibẹ yoo gboju kuro lọrọ awọn ṣẹṣẹ de to gbadajọ ẹwọn ni UK naa, Minisiri eto idajọ sọ fun akọroyin pe iyẹn ku sọwọ orilẹede wọn.

Itumọ eyi ni pe o ṣee ṣe kẹni to gbadajọ ẹwọn ni UK maa yan fanda bii alaiṣẹ to ba de ilu abinibi rẹ, ko ṣaa ti kuro lọdọọ tawọn ni.
Lọwọlọwọ, ida mejila ni awọn eeyan to jẹ ajoji ẹlẹwọn lorilẹde naa, ko si din ni £54,000 ti ijọba n na lori ibi ti wọn n fi wọn si bi ijọba ṣe ṣalaye.

Igbesẹ tuntun yii yoo ba UK din inawo ku, yoo si tun da aabo bo awọn eeyan to n sanwo ori lawujọ bi wọn ṣe sọ.

Awọn ti idajọ tiwọn ba jẹ ẹwọn gbere, awọn agbesunmọmi ati apaayan yoo lo abala idajọ ẹwọn wọn pari rẹ ni UK, ko too di pe wọn yoo ro o wo boya ki wọn fi wọn sọko siluu wọn.

Bi ofin yii ba bẹrẹ, o le kan awọn to wa lẹwọn lọwọlọwọ.

Eyi tumọ si pe ẹsẹkẹsẹ ni idapada sile ẹlẹwọn naa yoo bẹrẹ.

Ni akọsilẹ oṣu Kin-in-ni ọdun 2024, o to ẹlẹwọn ẹgbẹrun mẹwaa le ni irinwo, (10,400) ti wọn wa lẹwọn ilẹ okeere.

Akọwe idajọ, Shabana Mahmood, sọ pe awọn yoo juwe ile fun awọn ajoji ẹlẹwọn, bi wọn ba lufin bawọn ṣe gba wọn tọwọtẹṣẹ, tabi ti wọn tun lufin eyikeyi.