Oserebinrin ati oloselu ni, Tonto Dikeh, ti toka si aipeye re ti ko le se iranlowo fun un.
Se Yoruba bo, won ni ejo kii se ejo eni ka ma moo da.
Gbogbo eniyan ni o ni aipeye tiwon bo ti wu ki won lagbara ti won si mo iwa hu to.
Lori oro tire, o wi pe, oun to buru julo aile ma aba awon eniyan sore tabi ojulomo fun igba pipe.
Opo eniyan yoo ranti ilumooka okunrin ti a ma se bi obinrin ni, Idris Okuneye, ti a mo si Bobrisky, ti o je ore korikosun Tonto Dikeh ni igba kan ri ki won to pinya, eyi ti o yori si ija ti o yanilenu.
Tonto ti gba pe oun buru jai lati ni ore ati ba ojulumo kan se fun igba to pe.
Amo sa o, o wi pe, oun nife gbogbo won, awon ko kan le jo se wole-wode gbogbo igba ni.
O so pe,”LAASIGBO INU AYE MAA N JE KI ENIYAN GBAGBE LATI JE OLURANLOWO FUN AWON TI A FERAN. O JE OHUN TI KO MO MI LARA PUPO LATI MAA KO ORE ATI OJULUMO KIRI SUGBON MO FERAN GBOGBO YIN NI ONA TEMI TI O JE EEMO!!!
EMI NIYI TI MO N SO WIPE GBOGBO WERE AGBAYE, MO NI IRETI PE E WA DAADAA.”
Ibasepo awon gbajugbaja oserebinrin bii Toyin Lawani, Halima Abubakar, Anita Joseph, Swanky Jerry, Annie Idibia, Toyin Abraham ati bee bee lo ni o ti fori sanpon ni ona ti ko rorun.