Títa ríro làá kọ ilà, afẹ́fẹ́ ìdùnú pẹ̀lú ayọ̀ gbilẹ̀ lọ́gbà Fásitì Adekunle Ajasin

Títa ríro làá kọ ilà, afẹ́fẹ́ ìdùnú pẹ̀lú ayọ̀ gbilẹ̀ lọ́gbà Fásitì Adekunle Ajasin

Fẹ̀mi Akínṣọlá

Àwòràn wọ̀nyí ni ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde Fásitì Adekunle Ajasin tó wà ní ọgbà Mufutau Lanihun Ọremeji Ìbàdàn, lásìkò àpèjẹ àlẹ́ òhun ìmọrírì àwọn olùkọ́ ọ wọn, èyí tó wáyé lọ́jọ́ àbámẹ́ta ,ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù karùn-ún, ẹgbẹ̀rúnọdún okòólémárù-ún, lábẹ́ aṣojúdárí ilé ẹ̀kọ́ náà Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún Táíwó “GFR”
lásìkò tó n kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ,akọ̀wé àgbà tó ṣojú Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún Táíwó , Ṣheik Adébólú Sirajudeen fi iṣẹ jẹ pé, ìwúrí nlá ló jẹ́ fún òun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàmúlò ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ lọ́gbà Fásitì ọ̀hún.
Ó tẹ̀síwájú pé, ìtàn kìí parẹ́ , àti pé, ìtán ni wọ́n n kọ yìí fún àwọn ìran tì yóò kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lọ́gbà Fásitì yìí.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ,wọ́n ti bomi ọgbọ́n mu níbi tí odò ìmọ̀ gbé jìngòdò, látàrí èyí,kí wọ́n fọ́n sìnú àyé lọ fi orúkọ Fásitì yìí yàwòrán rere fún gbogbo àgbáálayé.