Tí mo bá jẹ́ Ààrẹ Naijiria, dúróònù ni màá fi se Minisita dìfẹ́ǹsì – Sowore

Tí mo bá jẹ́ Ààrẹ Naijiria, dúróònù ni màá fi se Minisita dìfẹ́ǹsì – Sowore

Yínká Àlàbí

Ọgbẹni Omoyele Sowore to dije du ipo Aarẹ Naijiria labẹ ẹgbẹ oselu AAC (African Action Congress) ni ọdun 2023, salaye pe ti oun ba jẹ Aarẹ orileede yii lasiko yii, duroonu (drone) ni oun maa fi se Minisita idaabobo (minister of defense).
Sowore salaye yii nibi eto araarọ kan ni ori ẹrọ tẹlifisọn Channels.
O ni ifowo sofo lasan ni baluu ogun ti Naijiria n kowo ra, wọn a si tun fi aimọye ọdun kọ wọn bi wọn se maa loo. Ni eyi to tumọ si pe ki “ilẹ to posika, ohun rere a ti bajẹ”.
Omoyele ni duroonu to maa se iru iṣẹ naa maa lowo lori diẹ sugbọn esi rẹ maa tẹ gbogbo aye lọrun.
O ni duroonu mẹwaa pẹlu eniyan marun-un to maa foju too, eyi maa tete ta awọn agbofinro lolobo ibi ti awọn onisẹ ibi n lugọ si.
Sowore ni “ duroonu maa sisẹ awọn agbenipa, ajinigbe ati awọn janduku agbebọn rin”. “Ijọba Naijiria ni lati kuro ni igbe aye atijọ ti ko tii si ẹrọ igbalode ti oju si wa lojugun”.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here