Soun kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jò mẹ́jọ fáwọn obìnrin l’Ogbomoso

Soun kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jò mẹ́jọ fáwọn obìnrin l’Ogbomoso

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní bí kò bá nídìí, obìnrin kìí jẹ́ ikúmólú, àṣamọ̀ yìí kò sé lórí bí Ṣọun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afọlábí Ọláoyè, ti kéde kónílé ó gbélé ọlọ́jọ́ mẹ́jọ fáwọn obìnrin nílùú Ogbomoso nítorí ọdún Orò.

Ọba Olaoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe Aafin Ogbomoso, Toyin Ajamu, fi sita.

Kabiyesi sọ ninu atẹjade naa wi pe lalẹ ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala ni konile o gbele ọhun yoo bẹrẹ.
Lati aago mejila oru ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa ni ọdun Oro naa yoo tí gbinaya.

Ọdun naa yoo maa waye lati ago mejila titi di ago mẹrin idaji lojoojumọ titi di ogunjọ ọjọ Ẹti ọsẹ to n bọ ti ọdun naa yoo kasẹ nlẹ.
Soun wa rọ awọn obinrin niluu Ogbomoso lati duro sinu ile wọn titi ti ọdun Oro naa yoo fi pari.

Kabiyesi tun sọ ninu atẹjade naa pe awọn ọlọpaa ni yoo gbe ẹnikẹni to ba tapa si ofin konile o gbele yii.

Bakan naa ni Ọba Ghandi sọ ninu atẹjade ọhun pe ko gbọdọ si ilu lilu lati ibẹrẹ titi de ipari ọdun Oro naa niluu Ogbomoso.

Soun rọ gbogbo olugbe ilu Ogbomoso lati fọwọ sowọ pọ ki ọdun Oro naa le kẹsẹ jari.