Lasun Alagbe
Gbajugbaja akorin, Yinka Ayefele, tun gbe omiran wolu laipe yii.
Awo orin re tuntun maa jade ni aipe yii, eyi to pe akole re ni SO FAR, SO GOOD.
Funra Ayefele lo so oro yii ni ojo die seyin, to si soro pelu ibale okan ati ireti nla pe ojo iwaju yoo daa, yo dun ju ti ateyinwa lo.
Sugbon ko tan sibe. Pelu bi Ayefele se di eni ibukun, o ni oun naa se tan lati bu kun awon odo.
O ti wa n se eto nla kan ti yoo fi ko won bi won se le lo ebun won ni ilana orin bii tire, ti awon naa yoo se di ilomoka ati olokiki.
Ayefele fe ki won mo pe kii se orin hip hop nikan ni won le ti fakoyo.
Nipa bee, yoo se imuniloriya ati danilekoo alagbeeka to si je pe eto naa yoo wa lori ero ayelujara.
Ayefele, eni to je pe Olorun ti bu kun gbaa, to je pe oro re ti koja akorin lasan, to je pe oun lo ni Fresh FM ti irawo re to tan kaakiri agbaye, so pe oun yoo se eto amoriya naa pelu ajosepo ile ise kan ti a mo si CKrowd Africa Technology and Solutions.
O wa ni lojo keedogban osu yi, iyen September 25, ni awon yoo se eto to pe ni Digital Music World Tour.
Laisi aniani, Ayefele ti di baba.
Olorun ti gbe e ga, ti Olorun si n fi oro igbesi aye re ko awon eniyan lekoo pe eni ti Oun ba ti wa leyin re, o da bii akuko ti yoo ko ni, ti asa kan ko le gbe.
KA MA BAA GBAGBE: Igbokegbodo Yinka Ayefele (Lati inu iwe IROYIN OWURO)
- Idaamu Ayefele ati oniruuru adanwo to ti ba awon agba akorin Yoruba
. Ajimobi pinnu lati saanu re leyin ti won ti wo ile
Otito ni pe ko si eniyan to koja adanwo. Sugbon nile aye, adanwo ti eni kan maa n ju ti elomiran lo.
Ti a ba wo awon ajalu ti akorin pataki, Yinka Ayefele, ti la koja, a maa ri i pe o je eni kan ti oju re ti ri mabo.
Loooto, lati ara adanwo naa ni Olorun ti so o di eni giga, sugbon oun ti oju asegita n ri kii se keremi.
Ti ode Ayefele ba si ro ise ro iya, to ba peran ko ni fun eni kan je.
A ko mo pupo ninu wahala ti oju re ti ri ki o to di odun 1997. Sugbon ohun to sele si okunrin naa ni odun yii kii se ohun ti eni kankan le maa gbadura ki oju ota oun ri.
Eyi ni ijamba moto buruku kan to so o di eni to n lo osu mesan-an gbako ni osibitu. Ni igbeyin-gbeyin, asidenti naa ko mu emi re lo, sugbon o so o di alaabo ara di oni olonii.
Lati ibi adanwo ijamba moto, o bo sinu adanwo eni ti ko le fi ese ara re rin mo, ti ko le da duro, ti ko si le se opolopo ohun ti egbe re n se. Ajalu moto naa lo so o di eni to n wa lori keeke alaileerin.
Oro naa le debi pe awon kan n ro pe boya ni okunrin naa le se ohun ti okunrin maa n se pelu obinrin mo. Sugbon riro ni ti eniyan, sise ni ti Oluwa. Gege bi akorin naa ti so, Olorun pa enu alabosi mo, to si je pe o si le n se okunrin lodo iyawo re.
Leyin ti kadara wa so Ayefele di eni nla, to ni owo, okiki ati ola ti awon olorin to lese mejeeji ko ni, a lero pe wahala ti tan laye re ni. Sugbon ohun to sele si okunrin naa lenu ojo meta yii fihan pe ko ri be e.
Eyi ni ede aiyede ati ija ajadiju to waye laarin oun ati ijoba Ipinle Oyo nigba kan lasikoGomina Oloogbe Isiaka Abiola Ajimobi , to fi di pe won wo lara ile re to wa ni Orita Challenge Ibadan.
Nigba ti awuyewuye naa koko bere, o dabi pe kannakanna p’omo ega ni, ija n bo, ija koi de. Bi ijoba se n leri ni Ayefele naa n leri. Lasiko kan, akowe iroyin re ana, Oloogbe David Ajiboye, tie so fun ijoba naa pe awon ko beru mo, ki o wa se ohun to ba fe. Idi nip e won gba pea won ko lebi rara.
Leyin eyi ni Yinka Ayefele gbe Ajimobi lo sile ejo.
Loooto, bi ariyanjiyan nla ba sele bayii, awon adajo je pataki ninu awon to maa n yanju re. Sugbon Yoruba naa lo bo ti won ni a kii ti kootu bo ka s’ore.
Ijoba Ipinle Oyo si duro lori pe awon setan lati wo ile Ayefele naa tori won ni akorin naa se sofin nipa kiko iru ile naa si orita naa.
A gbo pe won tin so pe ile oni oofisi rere, iye office complex, ni o ni oun yoo fi ko, ko to dip e o ko ile ibi ti won ti n sise redio ati orin, iyen studio.
Ibe naa ni ile ise redio Ayefele wa.
Ile ejo giga ti Oyo State High Court ni Ibadan ni Ayefele gbe ejo naa lo, pelu loya re, Ogbeni Olayinka Bolanle.
Adajo I. Yerima pase pe ki igbejo waye ni ojo Monday.
Bi gbogbo eyi se n lo, awon ololufe Ayefele ati awon osise re fi ehonu han ni ile ise naa.
Ni idaji Sunday ni awada di oooto. Ajalu nla wole ba akorin Tungba, Yinka Ayefele, nigba ti won gbe katapila bulldozer lo fa ile naa ya yannayanna mo ibi ti ina ti dahun.
***
Ayefele ba omokunrin je, o bu sekun gbagada!
Yoruba bo, won ni eni ti oro ko ba lo n pe ara re l’okunrin. Akorin pataki, Yinka Ayefele, lo le jeri si oro yi lowolowo yii.
Idi niyi ti o fi bu sekun gbagada ni Ibadan ni irole ojo kan, nigba to n ba awon oniroyin soro lori bi ijoba Ipinle Oyo se iwo ile ise redio re.
O ni gbogbo iwe to ye ki oun gba ni oun gba. O ni nigba ti wahala a o wole, a ko wole de, iyawo oun lo be Ajimobi lale ojo Satide molegbagbe. Ayefele ni Ajimobi so fun iyawo oun pe awon ko ni wo ile naa mo.
Koda, o ni Ajimobi fun iyawo oun ni nnkan alejo, eyi to je egberun dola kan – $1,000.
O ni eyi lo se ya oun lenu pupo nigba ti won tun gbe katapila de ni idaji Sunday molegbagbe kan.
Epe ti awon eniyan n se ko le ran mi tori n ko se aburu – Ajimobi
Gomina Ipinle Oyo nigba naa, Senito Abiola Ajimobi – ki Olorun dele f’eni to ti ku – soro lori bi ijoba re se wo lara ile akorin Tungba, Yinka Ayefele, ati epe pelu oro alufaasa ti awon eniyan ti fi n ranse si i.
Bakan naa, Ajimobi ni ijoba oun wo ile naa nitori Ayefele se si ofin ni.
O so fun ile ise iroyin BBC pe oun ko le so pe tori pe ile ise Fresh FM n pese ise fun awon eniyan tabi pe yefele je alaabo ara, ki oun maa wo won ki won te ofin loju.
O ni se ti adigunjale kan ba n gba awon eniyan sise, se ijoba a maa wo o niran ni?
Nigba ti Ajimobi tun n ba awon oniroyin soro lojo Ileya, Ajimobi ni gbogbo igbese ti oun n gbe lati igba ti oun ti gori aleefa, eyi to bofin eniyan ati ti Olorun mu ni.
O ni niwon igba ti oun ko ba se aburu, epe ila kii mu agborin, adura ni yoo maa se le oun lori.
O wa fi kun un pe ijoba oun yoo wo bi oun se le ran Ayefele lowo.
Ajimobi se ipade pelu Yinka Ayefele
Oro awon oloselu, nnkan nla ni. Eyi lo d’Ifa funOloogbe Ajimobi to tun se ipade irepo pelu Yinka Ayefele, ni ile ijoba to wa ni Ibadan.
Gomina wa so pe won maa da ajo komiti kan sile lati wo igbese ti won ni lati gbe lori isele ara ile Ayefele ti won wo ni Orita Challenge, Ibadan.
Opo eniyan lo bu enu ate lu gomina lori igbese ile wiwo naa, sugbon oun naa ni ika to ba se ni oba a ge ni oun se e.
Sugbon lasiko ipade naa, Ajimobi ni eniyan daadaa ni Ayefele, sugbon ko si anfaani ninu ki a maa se si ofin ile kiko.
Ayefele naa ni gbogbo ohun ti ijoba ni ki oun se ni oun se, sugbon awon ojise gomina ni ko fun oun laye lati ri i lasiko.
mmmmmmmmm
Idaamu Yinka Ayefele ati bi awon osere Yoruba se la oniruuru ajalu koja
Bi o tile je pe kii se gbogbo won ni ijoba wo ile won, opo awon osere Yoruba naa lo ti la laasigbo nla koja. Se eni ti yoo ga, ese re yoo tin-in-rin.
Eni kan pataki to koko maa n wa si okan awon eniyan niru asiko yii ni Fela Anikulapo-Kuti. O je eni kan to maa n ba ijoba fa wahala. Laye ijoba Obasanjo akoko, nigba to je ologun, won da awon soja si Afrika Shrine Fela to wa ni Jibowu ni Eko.
O buru debi pe Fela ni won ju iya oun sile lati ori oofusia, ti won sin a awon eniyan ni anaki ki won tun to fi ina si ile naa.
A ko si gbodo gbagbe pe opo igba ni won ju Fela si ewon. Eyin aasigbo naa ni Fela gbe awo orin UNKNOWN SOLDIER jade.
Olorin miiran to tun se agbako ijoba ni Oloogbe Hubert Ogunde. Laye oselu Awolowo, o gbe ere ati awo orin YORUBA RONU jade. Awon Awon ijoba Oloogbe Ladoke Akintola gba pe awon lo n ba wi. Nipa bee, won fiya je e.
Oloogbe Yusuf Olatuni ko jiya lowo ijoba, sugbon oun naa ri ajalu ijamba moto nla kan. Wahala naa le debi pe awon kan ni won ti gee se re nigba to wa ni osibitu. Leyin eyi ni Yusuf Olatunji korin Yegede won ko ge e…
Oloye Ebenezer Obey naa foju wina ri. Ina kan seru ba a nigba to sese n dide gege bi akorin. Eyi lo bi orin ‘Lopelope oyinbo onilekeji/ To n kigbe/ Faa…/ Faa../ Faaya faya ki panapana to de.”
King Sunny Ade naa maa ri wi ti won ba ni ko ro ti enu re. Ni asiko kan, o jiya pupo labe asia ile ise orin Abioro. Ni pataki, aisan nla kan se e ni nnkan bii odun 1991 to si je pe Olorun lo yo o.
Meloo ni a fe kan, meloo ni a fe wi? Awon sorosoro bii Olanrewaju Adepoju, Gbena Adeboye ati beee bee lo foju wina gidi. Leyin pe ijoba Babangida ba Lanrewaju Adepoju fa surutu, bi a se n soro yii, oju n dun un, ti ko si le da lo si ibi kankan. Ki Oba Olojo Oni da oju akewi pataki naa pada.
A ko le gbagbe orisiirisii adanwo ti Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister la koja. Lasiko kan, obinrin kan tie jade to ni oun ni oun bi i, bee Barrister mo pe Odere Sifawu ni iya oun. Iru awon wahala ti aye gbe si Dr Fuji nigba lo mu u korin OKIKI: “Okiki ti mo ni yi ko to o, Edumare/ Ba mi wa mii si o, Edumare…’
Leyin pe awon alaheso kede iku Kollington Ayinla bii eemeji, ina nla kan jo ile re ni Alagbado. Asiko naa ni iyawo re kekere kan to loyun ku, pelu iroyin pe won so pe ki o seyun ni. Alhaja Salawa Abeni ni won toka si. Ibinu eyi ni oun ati Kebe n Kwara fi ko ara won sile titi di oni olonii.to je ni o korin ‘Won so pe mo ku, ariwo gbale,/ Okiki kan ja gbogbo Naijiria….’
Dauda Akanmu Epo Akara naa kare lona orun. A ko le gbagbe bi moto oun ati awon elegbe re re se se konge ijamba moto ni eti Alapako lona Ibadan. Won n ti Eko ti won ti lo sere bo lojo naa ni. Eniyan mejeeji otooto – Omoboade ati Dauda – ni won je Olorun nipe nigba naa. Asiko yii ni Epo Akara korin ‘Ni o f’abo f’Olorun lorun/ Ni o f’abo f’Olorun lorun/ Asiko tonikaluku ba yan/ Asiko tonikaluku ba yan/ Ni o f’abo f’Olorun lorun…”
Bakan naa, a ko gbodo gbagbe pe Oloogbe Orlando Owoh lo si ewon lori esun igbo, to fi wa korn E GET AS E BE nigba to jade. E get as e be…, o nib o se je.
Ayinla Omowura ti ko wo ewon, gbogbo bo se lagbara to, won gun nigo pa ni. Eyi tumo sip e, loooto, ko si eni to koja adanwo.