Seyi kò gb’ọ́wọ́ sóke láti nà mí rí – Òsèrébìnrin Biola Bayo

Seyi kò gb’ọ́wọ́ sóke láti nà mí rí – Òsèrébìnrin Biola Bayo

Mary Fágbohùn

Oserebirin Biola Bayo ti tako iroyin nipa iwa-ipa abele ninu ikọsilẹ rẹ laipe.

Ó kéde ìyapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, Seyi, lọ́dún tó kọjá, ó sì so pe won fenuko lati se itoju omo won.

Biola ṣalaye lori Instagram pe wọ́n ko fi igba kan tahùn síra wọn tabi yo owo ija sira ninu igbeyawo wọn.

O ni ki awọn ololufe oun tesiwaju ninu adura fun wọn, o gba won niyanju lati maa soore fun awọn elomiiran, o ṣe akiyesi pe igba gbogbo ni awon eniyan n fi irora won pamo.

” Mo n soro nipa pe a o fi igba kan tahùn síra wa tabi yo owo ija sira lati ọdọ ọkan ninu wa. (Seyi ko gbe owo soke lati na mi ri bee ni emi naa ko ṣe bẹ rara). Ẹ jẹ ki a kọ ẹkọ lati je oloore si eniyan. E o mo ohun ti awọn miiran n la koja di igba ti wọn sọ, “gẹgẹ bi o se salaye.