Rògbòdìyàn tó fẹ́rẹ̀ já èrò sí ìhòhò ní pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed ni Ikeja
Yínká Àlàbí
Yatọ si ohun to jọ ere ori itage Wasiu Ayinde lọsẹ to kọja, edeaiyede miiran tun waye laarin ero kan pẹlu awọn osisẹ baluu Ibom Air Flight. Baluu naa de lati ilu Uyo si Eko. Ninu fidio to n kaakiri ori ayelujara, osisẹbinrin Ibom Air ke gbajare si awọn ọkunrin pe obinrin to jẹ ero ninu baluu naa ni o n salaye nnkan fun ti o si bẹrẹ si gba oun leti. Koda o n ba awọn nnkan inu baluu naa jẹ.
Eyi mu ki awọn ọkunrin ti wọn jẹ osisẹ papakọ naa sare si ohun to n sẹlẹ. Nigba ti agbara wọn ko fẹ ka obinrin naa mọ ni ọga wọn pase ki wọn gbe e kuro ninu baluu naa.
Ibi ti wọn ti n gbe ni irun oge jabọ, bẹẹ si ni ẹwu to wọ naa ya ko to de isalẹ. Ero yii naa n pariwo pe se wọn mọ ohun ti osisẹbinrin naa se fun oun ki oun to sọọ di ija fun un. O ni afi ki wọn gbe fidio inu baluu naa jade fun agbejọro oun. Fidio yii lo tun n ja raninranin bi ina ọyẹ lori ẹrọ ayelujara.