PDP kéde pé gúúsù Naijiria ni olùdíje sípò ààrẹ lọdún 2027 yóò tí wá
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti kéde pé ẹkùn gúúsù orilẹ-ède Nàìjíríà ni olùdíje sípò ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ náà yóò ti wá, fún ètò ìdìbò ọdún 2027.
PDP to jẹ ẹgbẹ alatako ni Naijiria kede ọrọ yii nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa, NEC, to waye niluu Abuja lọjọ Aje ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ.
Nibi ipade yii kan naa ti i ṣe ikejilelọgọrun un iru rẹ ni ẹgbẹ ọhun tun ti kede Umar Iliya Damagum gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa.
Ọgbẹni Damagum to ti wa nipo adele alaga gbogbogbo fun bi ọdun kan bayii ti di alaga ti gbogbo ile gba wọle ṣaaju ipejọpọ nla ẹgbẹ PDP ti yoo waye niluu Ibadan ipinlẹ Oyo, lọjọ kẹẹdogun ati ikẹrindinlogun oṣu Kọkanla ọdun yii.
PDP ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi sita pe niwọn igba ti ipo alaga ti lọ si ẹkun ariwa, ẹkun guusu ni oludije sipo aarẹ fun eto idibo 2027 yoo ti wa.
Loṣu Kẹta ọdun yii ni ẹgbẹ PDP yan Damagum gẹgẹ bi adele alaga lẹyin ti wọn ni ki Sẹnẹtọ Iyorchia Ayu lọ rọkun nle.
Igbimọ alaṣẹ PDP dupẹ lọwọ igbimọ awọn gomina, igbimọ adari, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba l’Abuja ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ fun ipa ti wọn ko lati ri pe ipade NEC ti wọn ṣe niluu Abuja lọjọ Aje kẹsẹ jari.
PDP tun gba abọ igbimọ to n ṣiṣẹ lori bi ipejọpọ ẹgbẹ naa ti yoo waye loṣu Kọkanla to n bọ yoo ṣe lọ ni irọwọ-rọsẹ wọle.
Nnkan mii tun ni pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni gbogbo oloye ẹgbẹ lati ẹkun ariwa to fi de guusu yoo maa tẹsiwaju pẹlu ipo wọn.
PDP ko ṣai fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣe ijọba lọwọ wi pe wọn fẹ fi tipa tipa ati eeru sọ orilẹede Naijiria di ẹlẹgbẹ oṣelu kan.
PDP ni eyi jẹyọ nibi atundi ibo waye kaakiri orilẹede Naijiria laipẹ yii.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni gbogbo igbesẹ ti APC n gbe lo tako ilana eto iṣejọba awarawa.
Awuyewuye ti wa lagbo oṣelu ni Naijiria lori ọrọ ibi ti oludije sipo aarẹ yoo ti wa fun eto idibo ọdun 2027.
Lọwọ yii, ẹkun guusu ni Aarẹ Bola Tinubu to wa lori aleefa lasiko yii ti wa.
Bakan naa, APC to jẹ ẹgbẹ oṣelu aarẹ ti fontẹ lu u gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ fẹgbẹ naa fun ibo aarẹ ọdun 2027.
Ti ẹ o ba gbagbe, ede-ai-yede bẹ silẹ nigba ti PDP kede Igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar, gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ ẹgbẹ naa fun ibo aarẹ ọdun 2023.
Igbesẹ naa ko dun mọ Gomina ipinlẹ Rivers nigba naa, Nyesom Wike, ninu, eyi lo si jẹ ki o kede atilẹyin rẹ fun Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2023.
Ni bayii ti PDP ko tii yan oludije sipo aarẹ ẹgbẹ naa fun eto idibo 2027, Wike, to jẹ minisita Abuja bayii kilọ fun PDP loṣu Karun un to kọja pe ẹgbẹ naa yoo kuna ti wọn ba mu oludije sipo aarẹ lati ẹkun ariwa.
Wike sọ pe ko ni mọgbọn dani bi ẹgbẹ alatako PDP ba lọ mu oludije sipo aarẹ lati apa ariwa nigba ti Aarẹ Tinubu ti yoo jẹ oludije fun APC wa lati ẹkun guusu.