Paul Biya, ààrẹ Cameroon láti ọdún 1982 tún fẹ́ dupò fún sáà kẹjọ

Paul Biya, ààrẹ Cameroon láti ọdún 1982 tún fẹ́ dupò fún sáà kẹjọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

N tó wuni ní-ín pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni lọ̀rọ̀ Ààrẹ
orílè-èdè Cameroon, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàdọ́rùún bó ti ṣe kéde yanya pé òun yóò tún du ipò Ààrẹ fún sáà kẹjọ lẹ́yìn to ti lo ọdún mẹ́tàlélógójì lórí oyè.

Paul Biya lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo X rẹ nibi to ti ṣeleri lati tan iṣoro ti orilẹede naa n koju.

Lati igba to ti gori aleefa lọdun 1982, Biya lo n bori gbogbo ibo aarẹ ti wọn n di ni Cameroon lati ọdun naa.