Pastor Adeboye ríran rí ọjú ikú rẹ̀ pé Sunday ni

Pastor Adeboye ríran rí ọjú ikú rẹ̀ pé Sunday ni

Yínká Àlàbí

Nipa ipagọ ẹẹkan lọdun to pari ni ọjọ Satide, ọjọ kẹsan an osu kẹjẹ, ọdun 2025 yii ni oludasile ile ijọsin RCCG (Redeemed Christian Church of God) ti n salaye yii fun awọn ijọ.
Baba Adeboye ni oun maa pada sọdọ Ọlọrun lai mariwo tabi aisan dani. “Maa ku ni ọjọ isinmi lẹyin ti mo ba ti sọọsi de, ti mo si jẹ iyan to jẹ ounjẹ ti mo fẹran ju tan, ko ni si irora tabi inira kankan”.
G.O pe gbogbo awọn onigbagbo ododo nija lati fi adura gba ẹtọ wọn lọwọ Ọlọrun. O ni ki wọn ma gbagbe Israelites ti wọn ja fitafita ki wọn to de ilẹ ileri. “Ni ọpọ igba, wa a ja pẹlu adura kikan-kikan lati gba iwosan, ilọsiwaju, ọmọ bibi ati ẹmi gigun”.
Baba ni Jesu Kirisiti  (John 10:10) jẹ ko ye wa pe, a ni lati kọ aisan pẹlu igbagbọ gidi. O ni Ọmọ Ọlọrun si ti se gbogbo isẹ silẹ fun wa, pẹlu idi eyi, a ko gbọdọ saisan bẹẹ ni a ko gbọdọ talaka bi ekute sọọsi nitori pe a ni Ọlọrun.
“Onigbagbọ gidi kankan ko gbọdọ kaarẹ nibi adura pẹlu apẹẹrẹ Rachel ati Hannah inu Bibeli ti Ọlọrun pada da lohun pẹlu aisinmi adura ati igbagbọ ninu Ọlọrun”.
Oludasilẹ ijọ yii ni ki a ma se gbagbe pe Esu gọ sibikan lati le jẹ ki ọkan wa saarẹ, sugbọn a ko gbọdọ gba fun un. Baba fi apẹẹrẹ Jacob bi ko se gba fun Angẹli kan ninu iwe mimọ (Genesisi 32). O ni iku, aisan, osi, isẹ, airọmọbi ati adanu kii se ti ọmọ Ọlọrun.