Pagidarì ! Ọ̀gá àwọn sọ́jà pátápátá nílẹ̀ yìí ,Lagbaja jáde láyé

Pagidarì ! Ọ̀gá àwọn sọ́jà pátápátá nílẹ̀ yìí ,Lagbaja jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kan kò sí, Ọ̀run nìkan là rè è dé
Ọ̀gágun Taoreed Abiọdun Lagbaja, tí i ṣe olórí àwọn sọ́jà, ti padà f’ayé sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Orílẹ̀ Bọla Ahmed Tinubu ṣe kéde rẹ̀ láàárọ̀ Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹfà, oṣù yii, lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kọkànlá yìí, ni ọkùnrin náà jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56).

Gẹgẹ bi atẹjade ti Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin ṣe sọ, o ni ọkunrin naa mi eemi ikẹyin lẹyin ọpọlọpọ aisan niluu Eko, lalẹ Tusidee.

“Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 1968, ni wọn bi Lt. General Lagbaja, ti Aarẹ Tinubu si yan an bii olori awọn ṣọja lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.

“Iṣẹ ologun ti o yan laayo, ti o si tibẹ laamilaaka bẹrẹ nigba to wọ ileewe ti wọn ti n kọṣẹ ogun jija lorilẹ-ede yii, Nigerian Defence Academy (NDA), lọdun 1987.

Lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1992, o di ipo ọga ti wọn n pe ni Second Lieutenant mu lẹka ileeṣẹ ologun Nigerian Infantry Corps, gẹgẹ bii ọkan lara awọn ikọ ọmọ ogun ẹlẹẹkọkandinlogoji, 39th Regular Course, ti wọn jọ kẹkọọ jade.

“Ni gbogbo asiko to wa lẹnu iṣẹ ni Ọgagun Lagbaja fi ṣiṣe akin, to si jẹ adari Pataki, eyi to fi han pẹlu bo ṣe jẹ adari ikọ 94 Battalion, ati 72 Special Forces Battalion.

“Oniruuru ipa ribiribi lo ko ninu eto aabo abẹle, bii Operation ZAKI, nipinlẹ Benue, Lafiya Dole, nipinlẹ Borno, Udoka, ni apa Ila Oorun orilẹ-ede yii, ati Operation Forest Sanity, to waye lawọn ipinlẹ Kaduna ati Niger.

“Oloogbe tun kẹkọọ nileewe ti wọn ti n kọṣẹ ogun jija l’Amẹrika, iyẹn US Army War College, to si tun gboye imọ ijinlẹ onipele keji (Master’s Degree), ninu imọ Strategic Studies. Gbogbo eyi lo ṣafihan bo ṣe ni in lọkan lati gbe iṣẹ ologun ga, ati iwa akọṣẹmọṣẹ to n fi han gẹgẹ bii adari nileeṣẹ ologun”.

Iyawo rẹ, Mariya, atawọn ọmọ meji ni Lagbaja fi silẹ lọ.

“Aarẹ Tinubu ba awọn mọlẹbi ẹ ati agbarijọpọ ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria kẹdun ẹni wọn to lọ lasiko to nira fun wọn yii. O gba a laduura pe ki Ọlọrun fun ẹmi Ọgagun Lagbaja nisinmi, ki o si san an lẹsan ipa ribiribi to ko lori orilẹ-ede yii”.

Ki a ranti pe, Aarẹ Tinubu ti yan Olufẹmi Oluyede, bii adele ọga awọn ṣọja lọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, nigba ti Lagbaja ti wa lori akete aisan.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla yii, lo fi kun okun si apa Oluyede, ti wọn si gbe e ga si ipo lieutenant-general.

Ọpọ awọn ologun atawọn ti wọn mọ ọkunrin akikanju yii ni wọn ti n ba mọlẹbi rẹ daro.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here