Oyingbo si Agbado: Ò̩gò̩ò̩rò̩ ènìyàn yòm̀bó Sanwo-Olu bí o̩kò̩ ojú irin Red Line s̩e bè̩rè̩ isé̩

Oyingbo sí Agbado: Ò̩gò̩ò̩rò̩ ènìyàn yòm̀bó Sanwo-Olu bí o̩kò̩ ojú irin Red Line s̩e bè̩rè̩ isé̩

Akeem Lasisi

Yoruba bo, won ni bi eegun eni ba n joo re, ori a maa ya atokun.

Bee, yinni-yinni keni o se omiran.

Eyi lo fa a ti ogooro eniyan fi n gbe oriyin fun Gomina Ipinle Eko, Alagba Babajide Sanwo-Olu, lori bi oko oju irn Red Line se bere ise ni ipinle naa.

Nnkan bii ose meji seyin ni Sanwo-Olu kede pe Red Line, eyi to n na Oyingbo si Agbado, ti di ohun amulo fun awon ara Eko wenjele.

Idi niyii ti igbe ayo fi ta, ti awon eniyan si n rojo oro idunnu, iwuri ati imoore le gomina naa lori.

Lori redio, telisfisan, ninu iwe iroyin ati lori ero ayelujara, aimoye eniyan lo n se sadankaata fun Sanwo-Olu.

Oun naa wa mu u da won loju pe keesekeese ni won tii ri o, kaasakaasa n bo lona.

O ni ijoba oun ti bere ise lori Green Line, eyi ti yoo lo si Epe Onikurani.

Nipa bayii, Ipinle Eko yoo wa ni akanse irinna reluwee meta – iyen Red Line, Green Line ati Blue Line, eyi to ti n sise laikose lati nnkan bii odun meji seyin.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here