Oxlade ní ọwọ́ Fireboy lòun ti kọ́ isẹ́ orin
Mary Fágbohùn
Olorin takasufe, Oxlade, ti safihan pe o lo se bi won se n ko orin daadaa lati odo akegbe re, Fireboy DML.
Olorin ‘Kulusa’ naa salaye pe idaleko ti Fireboy fun oun ran ise orin oun lowo pupo, to si yipada.
O so siwaju sii pe bi Fireboy se n ko orin re ko legbe ni ile ise orin Naijiria.
“Nigba to ba debi pe ki a ko orin sile, ko si elegbe re [Fireboy]. Mo ko bi won se n ko orin lati odo Fireboy.
“O wa lara iyipada si bi mo se n korin to dara saaju ki n to maa se nnkan mi. Idalekoo re yi aye mi pada,” Oxlade so eyi ninu fonran kan pelu gbajumo aderinposonu, Shank Comics.