Owó tíjọba àpapọ̀ jẹ́ Osun tó N6bn, gómìnà, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti Davido ni wọn ń pawọ́pọ̀ sanwó òṣìsẹ́ – Bode George
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọn ní bí ajá kò bá rí kìí dédé gbó.
Ní nǹkan bíi oṣù kan sẹ̀yin ni ẹnu bẹ̀rẹ̀ sí í kun Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ademola Adeleke, pé ó fẹ́ kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó gbé e wọlè.
Awuyewuye naa gbilẹ nigba naa, ọpọ eeyan si n sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ni gomina Osun naa n ba sọrọ lati di ara wọn.
Gomina Adeleke pada sọ pe irọ ni eyi, ati pe PDP loun tọkan-tọkan lọjọ kọjọ.
Ariwo ọrọ naa si ṣe bẹẹ lọ silẹ wẹlo lai mọ otitọ ọrọ to wa nidi isẹlẹ naa.
Ṣugbọn Oloye Bode George, eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati ọkan lara ọmọ igbimọ majẹobajẹ ẹgbẹ oselu naa, ti ṣalaye pe Adeleke fẹẹ fi PDP silẹ nigba naa loootọ.
O ni ọrọ ti oun ba a sọ ni ko jẹ ko lọ mọ
Nigba to n ṣalaye ọrọ yii lori eto ori redio kan, nipa bi Adeleke se fẹ kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP, Alagba Bode George sọ pe:
” Nigba to pe mi lorii foonu, o sọ fun mi pe oun fẹ fi ẹgbẹ PDP silẹ. Eyi jọ mi loju pupọ, o si ya mi lẹnu.
” Mo waa sọ fun un pe Ọlọla julọ, ro o daadaa o. Ṣe o mọ pe o ko gbọdọ ṣe aṣiṣe kankan bayii.
” Ṣe o ranti bi ẹgbọn rẹ, Serubawọn, ṣe lọ. Bi iwọ naa ba ṣe nnkan kan ti ẹgbẹ fi dibo abẹle, ti wọn fa ẹlomi-in kalẹ, o lọ niyẹn o.”
Alagba Bode Geoge tẹsiwaju, pe oun mọ pe Adeleke n gbiyanju fun ipinlẹ Osun, o si ni ifẹ awọn eeyan rẹ lọkan.
O ni ijọba apapọ ko sanwo to yẹ ko san fun awọn ijọba ibilẹ l’Osun lati bii oṣu marun-un si mẹfa bayii.
Gomina Ademola Adeleke pẹlu ẹgbọn rẹ ati Davido lo ni wọn n sowọ pọ ti wọn si n sanwo awọn oṣiṣẹ naa lapo ara wọn.
Owo to to biliọnu marun-un si mẹfa lo ni ijọba apapọ n jẹ ijọba Osun, ti kootu si ti paṣẹ pe ki wọn san an, ṣugbọn ti wọn ko mu aṣẹ naa ṣẹ.
”Lẹyin ọrọ ti mo ba a sọ ni mo ri Demola ni ipade ẹgbẹ wa, o si wa di mọ mi, o dupẹ lọwọ mi, o ni oun ko fi ẹgbẹ silẹ mọ.
” O n ṣe ẹtọ rẹ bii ọmọ ẹgbẹ, o si n wa si ipade bayii.”
Bẹẹ ni Oloye Bode George sọ.