Ọwọ́ tẹ dókítà àwọn bandiiti

Ọwọ́ tẹ dókítà àwọn bandiiti

Yínká Àlàbí

Àwọn agbofinro ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (DSS) ti mú dókítà kan tí ó ń rù àwọn ohun èlò ìtọ́jú láti ìpínlẹ̀ Sọkótó sí ọ̀dọ̀ àwọn ajinigbé tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ibi ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara jẹ́rìí síí ọ̀rọ̀ naa ní ojú-ewé Facebook wọn ní Ọjọ́ Jímọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìkéde náà ṣe jáde, wọ́n dá ẹlẹ́sẹ̀ náà dúró ní ìjọba ìbílẹ̀ Jẹbba, Moro, lẹ́yìn tí alamí sọ wọ́n, wọ́n gbà pé, ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pèsè àwọn ohun èlò ìṣègùn fún àwọn ènìyàn burúkú.
Dókítà yìí kan naa ni wọ́n rí ọwó rẹ̀ nibi oogun kíkó láti Sọkótó fún àwọn ajinigbé ní apá kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.
“Wọ́n dá dókítà náà dúró ní agbègbè Jẹ̀bba lẹ́yìn tí wọ́n gba ìmọ̀ràn nípa bí àwọn ajinigbé àti àwọn tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́.
“Àwọn ọ̀tẹlẹ́muyé náà funra pé ó dà bí ẹni pé àwọ́n bandiiti ń wá ìtọju lọ́wọ́lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fara gbà ibọn nígbà tí wọ́n pàdé àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò.”
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jo, won si foruko boo lasiri.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here