Òsèré tíátà mìíràn ní iró̩ ni Lalude àti àwo̩n tó kù ń pa nípa ìlérí M C Oluo̩mo̩
Mary Fágbohùn
Osere tiata, Alhaji Babatunde Bamgbode, ti a mo si Baba Fokoko, ti tako oro awon akegbe re lori ipolongo ibo 2023
E ranti pe Lalude, Alapini, Toyin Abraham, Olaiye Igwe, Seyi Law, Eniola Badmus ati Foluke Daramola wa lara ogooro awon ilumooka Nollywood ti won saaju ipolongo ibo fun iyansipo Aare Tinubu lasiko eto idibo gbogbogbo 2023.
Lasiko to n kabamo leyin odun meji isegun Tinubu, Alapini ni Osu Kefa 2025, ni oun ko ri nnkankan bii ere leyin akitiyan oun lati polongo ibo.
Lasiko to n soro nipa iforo-wani-lenu-wo Alapini, Lalude pe Aare awon awako (National Union of Road Transport Workers, NURTW), MC Oluomo jade pe ko mu ileri to se fun won ninu ipolongo naa se.
Amo sa, eni to soro ninu iforo-wani-lenu-wo lori mohunmaworan Oyinmomo TV, osere tiata Fakoko tako oro Lalude, o ni MC Oluomo ko seleri lati fun won ni ohunkohun.
“Ko seleri lati fun wa ni eyikeyi ebun. Ko seleri fun emi sugbon o ni lokan lati toju wa. O ti ju odun meji lo bayii! Ko seleri lati fun enikeni ni ohunkohun.
“O ra ounje fun wa lati pin lasiko ipolongo ibo naa, o si ni ka pin iyoku laarin ara wa. A lo sile pelu ounje ju igba meji lo. Sugbon ko figba kan seleri lati fun wa ni ohunkohun leyin ipolongo ibo”.