Orí kó K1 De Ultimate yo̩ nínú ìjàm̀bá bàlúù

Orí kó K1 De Ultimate yo̩ nínú ìjàm̀bá bàlúù

E̩ wo fidio ibi ti ori ti ba Wasiu Ayinde se e. “Ori lo ba mi se e”

Yínká Àlàbí

Yorùbá bò̩, “wo̩n ni ibinu ko mo pe olowo oun ko le̩se̩ nile”. Ibe̩re̩ ija ni a maa n mo̩, ko se̩ni to mo̩ opin re̩.
Ede aiyede lo waye laarin gbaju-gbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde nigba ti o fe̩ wo̩ baluu lati Nnamdi Azikwe International Airport, Abuja pada si Eko ni o̩jo̩ ise̩gun.
Awo̩n alamojuto baluu ni ofin ko gba e̩nike̩ni laaye lati gbe o̩ti lile wo̩ inu baluu, ayafi awo̩n eniyan ko̩o̩ko̩n to si ni iwe ase̩ dokita lo̩wo̩.Be̩e̩ ni K1 si gbe nnkankan sinu fulaasiki to gbe dani. O ni omi lo wa nibe̩, oun si fe̩ ki wo̩n gba oun gbo̩ nitori pe odu ni oun ti kii se aimo̩ f’oloko gbogbo wo̩n.
Nigba ti awo̩n alamojuto baluu naa ko gba, K1 fi ibinu da ohun to wa ninu fulaasiki naa sile̩ to si ta si awo̩n alaabo baluu naa lara ni eyi to je̩ ki wo̩n gbagbo pe oti lile ni.
Wo̩n ko je̩ ki o̩ga Fuji yii wo̩ inu baluu ni eyi ti o mu ki oun naa duro si iwaju baluu naa nigba ti wo̩n pa ilekun de. K1 ni baluu naa ko ni gbera lai gbe oun.
Bi pailo̩o̩ti se sana si baluu lati gbera ni Wasiu Ayinde sare be̩re̩ ori ki apa baluu naa ma baa gee lori. Koda ori lo ko awo̩n to n paro̩wa sii naa yo̩ lo̩wo̩ ijamba naa. Awo̩n naa sare be̩re̩ ori.
Kia ni o̩ro̩ naa de o̩do̩ awo̩n alase̩ baluu NCAA ( Nigeria Civil Aviation Authority) wo̩n si ti ni ki awo̩n osise̩ baluu mejeeji to gbera naa ma se fo̩wo̩ kan baluu kankan mo̩ ti iwadii se maa pari, wo̩n gba iwe irinna lo̩wo̩ wo̩n. O̩ga agba ileese̩ naa, O̩gbe̩ni Michael Achimugu ni awo̩n gbo̩do̩ ko̩ko̩ ba wo̩n wi nitori ofin ileese̩ ni lati ko̩ko̩ daabo bo e̩mi ati dukia ki nnkankan to te̩le e.
Valuejet ni oruko̩ baluu naa nigba ti no̩mba ara re̩ je̩ CRJ-900ER ati 5N-BXS.
Oruko̩ awo̩n awa baluu naa ni
Pilot, Captain Oluranti Ogoyi, ati Co-Pilot, First Officer Ivan Oloba.

E̩ wo fidio ibi ti ori ti ba Wasiu Ayinde se e. “Ori lo ba mi se e”

https://www.facebook.com/Yorubawoodcommunity/videos/1411982333365479/?mibextid=rS40aB7S9Ucbxw6v