Ọpẹ́ o! Àwọn tí wọ́n jí gbé l’Eruku gba ìdándè- Ààrẹ Bola Tinubu

Ọpẹ́ o! Àwọn tí wọ́n jí gbé l’Eruku gba ìdándè- Ààrẹ Bola Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé àwárí ni obìnrin wá nnkan ọbẹ̀.
Ààrẹ orílẹ̀èdè yìí, Bola Ahmed Tinubu, ti kéde pé àwọn èèyàn méjìdínlógójì (38) tí àwọn ajínigbé ji gbé ní ṣọ́ọ̀ṣì CAC Òkè-Ìṣẹ́gun, níìpínlẹ̀ Kwara, ti gba òmìnira.

Irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni Aarẹ Tinubu kede bẹẹ loju opo X rẹ.

Nigba to n ṣalaye itusilẹ naa, Aarẹ Tinubu sọ pe :

“Ẹ o ranti pe mo fagile irinajo mi lọ sibi ipade G20 to yẹ ko waye lorilẹede South Africa, lati le mojuto aabo nile.

“Ọpẹ fun awọn ẹṣọ alaabo wa lati bii ọjọ meloo sẹyin, gbogbo awọn olujọsin 38 ti wọn ji gbe ni Eruku, ipinlẹ Kwara ni wọn ti ri idande bayii.”

Bakan naa ni Aarẹ fi kun un pe mọkanlelaaadọta (51) ninu awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe nile ẹkọ awọn Katoliiki nipinlẹ Niger ni wọn ti pada sile .

“Mo n tọpinpin bi eto aabo ṣe n lọ kaakiri orilẹede Naijiria , mo si n gba iroyin nipa bo ṣe n lọ”

Gẹgẹ bo ṣe wi, Tinubu ni oun ko ni i sinmi lori eto aabo, o ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni ẹtọ si aabo to peye.
Labẹ iṣakoso oun si ree, oun yoo ri i pe oun da aabo bo awọn ọmọ Naijiria bo ṣe yẹ

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here