Ọọni sọ Olurẹmi Tinubu di “Yèyé Asíwájú Gbogbo Ilé Oòduà.”

Ọọni sọ Olurẹmi Tinubu di “Yèyé Asíwájú Gbogbo Ilé Oòduà.”
Yínká Àlàbí
Òọ̀ni Ilé-Ifẹ̀, Ọba Adeyeyẹ Ogunwusi, ti fún Iyàwó Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà, Seneto Olúremí Tinubu, ní oyè tuntun “Yèyé Asíwájú Gbogbo Ilé Oòduà.”
Ìwúyè náà wáyé ní Aafin Ilé-Ifẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú, tí ó sì se deede pelu iwuye odun kewaá Ooni.
Ara awon eniyan jankan jankan to peju pese sibi ayeye naa ni Aare teleri ní orileeede yii Olusegun Obásanjọ́ àti Sultan Sọkótò, Oòni sọ pé Seneto Tinubu bójú-tó ìṣẹ́ àṣà, ìṣàkóso àti ànfààní fún ile Yorùbá, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbe oye nla bẹ́ẹ̀ fun un.
Iyawo Ààrẹ dúpẹ́ gan-an, ó sì ní orúkọ náà jẹ́ iyì àti ẹ̀yẹ tó lágbára. Ní ọdún kan ṣoṣo, ó ti gba ọ̀pọ̀ oyè, bíi Iya Ọba Ikorodu, Ugosimba ní Enugu, àti Sarauníyàr Yaki ní Gombe.
Ayẹyẹ náà kun fún orin, ìjo àti àfihàn àṣà, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń yọ̀ ayọ ọ̀̀dún kẹ́wàá Oòni.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here