Oníṣẹ̀ṣe yarí ní ìpìnlẹ̀ Ògùn, wọ́n ní àwọn ń lọ sílé ẹ̀jọ́ bí wọ́n ṣe lé wọn níbi ìsìnkú Awujalẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn oníṣẹ̀ṣe ìpínlè Ògùn ti korò ojú sí bí àwọn kan ṣe lé àwọn ẹlẹ́sìn ìbílè kúrò nílé Awujalẹ ilẹ Ìjèbú, Ọba Sikiru Kayode Adetona, lásìkò ètò ìsìnkú rẹ̀
Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2025 ni Awujale darapọ mọ awọn babanla rẹ ti ọpọ eeyan kaakiiri agbaye si ṣedaro ori adẹ ọhun.
Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn fidio kan bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara, nibi ti awọn kan ti n le awọn oniṣẹṣe kuro nibi eto isinku naa.
Ohun ti a gbọ ni pe, lootọ ni wọn le awọn kan jade nile oloogbe ọhun amọ oun ko le sọ boya oniṣẹṣe ni wọn le tabi bẹẹ kọ.
Ninu ọrọ ti rẹ agbẹjọro ati alakoso awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ogun, Oloye Ifasola Opeodu, to jẹ Oluwo Iperu fidi iroyin naa mulẹ, o si ṣalaye pe awọn to le awọn oniṣẹṣe kuro nibi eto isinku naa ti ṣẹ si ofin ijọba ipinlẹ Ogun.