Ọmọ méjì da èmi àti Sẹgun Ogungbe pọ̀ sùgbọ́n a kò f’ẹ́ra – Omowunmi Ajiboye

Ọmọ méjì da èmi àti Sẹgun Ogungbe pọ̀ sùgbọ́n a kò f’ẹ́ra – Omowunmi Ajiboye

Mary Fágbohùn

Gbajugbaja oṣere tiata, Omowunmi Ajiboye, ti sọrọ sita lori ajọsepọ to wa laaarin oun ati akẹgbẹ rẹ, toun naa jẹ ilumọọka oṣere tiata, iyẹn Segun Ogungbe.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipe yi, Ajiboye ni won ko ṣe igbeyawo tabi ni erongba lati fẹ ara won.

O ni Segun Ogungbe ko mọ awọn mọlẹbi oun yatọ si ọrẹ aburo oun kan to mọ ni ilu Eko.

Agba oṣere naa, to bi ọmọ meji fun Segun Ogungbe wa rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ṣe pẹlẹ pẹlu rẹ nitori ko ki n ṣe eeyan buruku.

Wunmi sọ ninu ifọrọwerọ naa to ṣe wí pe nigba ti oun wa ninu igbesi aye Segun Ogungbe, nnkan dara fun un, ti nnkan si tun dara fun nigba ti oun kuro ni ile rẹ.

“Ẹ jẹ ki n sọrọ yii, ko tan, emi ati Segun Ogungbe, a ko ṣe igbeyawo tabi ni erongba pe a o fẹ ara wa.

Ko mọ mọlẹbi mi, yatọ si ọrẹ aburo mi kan to n gbe ni Eko. Segun funrara rẹ le jeri si oro yi.

“Si awọn ololufẹ mi, mo n rawo ebe si yin pe ki e se pẹlẹ pẹlu mi.

Mi o ki n ṣe eniyan buruku, mi o si ba aye Segun Ogungbe jẹ.

“Nigba ti mo wa ninu aye rẹ, nnkan lọ daada fun, nigba ti mo kuro, ko yipada, nnkan si n lọ daadaa fun un.

“Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ki n gbadun aye mi. Mo gba adura pe ile yin o ni bajẹ,” ni Wunmi sọ.

Ọdun 2023 ni ipinya waye laaarin Segun Ogungbe ati Wunmi Ajiboye lẹyin ti wọn bi ọmọ meji fun ara wọn tán.