Ọmọ lánlọọ̀dù gún ayálégbé baba rẹ̀ pa

Ọmọ lánlọọ̀dù gún ayálégbé baba rẹ̀ pa

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹni bá pe soso,ó di dandan kí ó rí soso
lọ̀rọ̀ dà báyìí,bí àwọn ọlọ́pàá téṣàn agbègbè Ilajẹ-Ajah, ní ìpínlẹ̀ Èkó, ṣe ń wá Ọ̀gbẹ́ni Taiwo Adebayọ, ọmọ bàbá onílé kan tó wà l’Ójúlé kẹrìnlélógún, Òpópónà Adewumi, nílùú Ilajẹ-Ajah. Ẹ̀sùn táwọn ọlọ́pàá fi kàn án ni pé ó gún Olóògbé Shina Oluwaṣẹgun tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn ayálégbé bàbá rẹ̀ pa nítorí ààyè ìgbọ́kọ̀sí táwọn méjèèjì ń jà sí

Oun tí a gbọ́ ni pé ní àsálẹ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkàndílógún, oṣù Kọkànlá yìí, ni Taiwo lọ jí olóògbé náà lẹ́yìn tó ti sùn lẹyin tó dé láti ẹnu iṣẹ́ dẹrẹba ọkọ akerò tó ń ṣe lágbègbè náà pẹ̀lú mọto kórópe rẹ̀ kan. Ohun tí Taiwo ń fẹ́ lọ́wọ́ olóògbé náà ni pé kó wáá gbé mọ́tò kórópe tó fi ń ṣiṣẹ́ kúrò níbi tó páàkì rẹ si, wọn ni ibi to gbe e si ko bojumu. Ṣugbọn nigba ti oloogbe maa debi to paaki mọto rẹ si o ri i pe ibi gan-an toun maa n paaki ọkọ oun si lati aimọye oṣu sẹyin naa lo wa. Gbogbo akitiyan oloogbe lati sọ fun ọmọ baba lanlọọdu rẹ pe oun ko kọja aaye oun ni ko wọ ọ leti rara, to si faake kọri pe afi ko gbe mọto rẹ kuro nibi to wa. Bi oloogbe ṣe wọnu mọto naa lati wa a kuro ni Taiwo bá tún yọ ọbẹ aṣóóró kékeré kan to wa lapo rẹ jade, to si bẹrẹ si i fi gun olóògbé yánnayànna ni gbogbo ara.

Ọgbẹni Matthew toun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ayalegbe ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sọ pé niṣoju oun niṣẹlẹ ọhun fi waye, ati pe ariwo lasan lawọn mejeeji n pa mọ ara wọn telẹ, nigba to ya ni oloogbe ba gbiyanju lati gbe mọto rẹ kuro nibi to n bi Taiwo ninu, láì mọ pé ọbẹ wà lọ́wọ́ Taiwo, tó sì fi gún un pa.

Ọgbẹni Shonibarẹ Faid tí í ṣe ẹgbọn olóògbé náà loun gba ipe pajawiri kan ni, nigba toun si maa dele taburo oun n gbe, ṣe loun ba a ninu agbara ẹjẹ to ti ku silẹ, ati pe mọṣuari ileewosan ‘Mainland Hospital, to wa niluu Yaba, nipinlẹ Eko lawọn gbe e lọ.

Ó ní, ‘‘Mo ti lọọ fiṣẹlẹ náà tó àwọn ọlọ́pàá agbègbè ibi tí àbúrò mi ń gbé létí, mo ṣalaye gbogbo ohun tawọn eeyan sọ fun mi nipa iṣẹlẹ to gbẹmi rẹ fun wọn pata. O yẹ ka ti lọọ ṣeto isinku rẹ ni ilana ẹsin Islaamu, ṣugbọn awọn ọlọpaa lo ni ka duro na, kawọn ṣayẹwo sara oloogbe naa lati mọ koko ohun to pa a.

Ohun tó ń bí mi nínú nípa ọrọ̀ ọ̀hún ni pé àwọn kọọkan tọrọ náà ṣoju wọn sọ pé ṣe niya to bi ọdaran náà, ìyẹn ìyàwó lanlọọdu, ń sọ fọmọ rẹ̀ pé kó tẹra mọ́ bó ṣe ń gún olóògbé títí tó fi kú.

Àti ìyàwó onílé tí í ṣe ìyá tó bí Taiwo, àti àwọn aráalé gbogbo ni wọ́n ti sá lọ báyìí, ìbẹrù pé káwọn ọlọ́pàá má wàá kó gbogbo wọn fóhun tí wọn kò mọ̀ nípa rẹ̀ tàbí káwọn ọdọ àdúgbò tínú ń bí wáá kojú ìjà sí wọn ló fà á tí wọ́n fi sá kúrò nílé báyìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here