Omíyalé pa ọgọ́rùn-ún èèyàn ní ìpínlẹ̀ Niger, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣègbé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ó ti tó ogórùn-ún kan àti méwàá èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn báyìí nínú ìjàǹbá omíyalé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Niger.
Adele ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger, (Niger State Emergency Management Agency) NASEMA, Dokita Ibrahim Husain, fidi onka naa mulẹ fun akọroyin.
Gẹgẹ bo ṣe wi, Alẹ Ọjọruu ọsẹ yii ni iṣẹlẹ omiyale ọhun waye nijọba ibilẹ Mokwa.
Ojo nla to rọ lo fa a ti omi fi ya bo awọn ile kiri, to ba ọpọ ile itaja jẹ pẹlu awọn ọja ti wọn n ta.
Ojo naa ko ṣai ba awọn nnkan oko jẹ pẹlu, bi alaye ti wọn ṣe.
Atẹjade ti NASEMA fi sita l’Ọjọbọ, ṣalaye pe agbegbe meji ni idaamu omiyale naa ba.
Awọn adugbo naa ni Tiffin Maza ati Anguwan Hausawa to wa niluu Mokwa, nijọba ibilẹ Mokwa.
“Ojo nla rọ fun ọpọ wakati, bẹẹ ni àgbàrá ojo bẹrẹ si i pọ si i to si n bo awọn ile mọlẹ.
“Omi naa bo ile to le ni aadọta (50), mọlẹ pẹlu awọn eeyan to wa ninu rẹ.”
Bẹẹ ni atẹjade NASEMA wi.
Ajọ naa ni oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ibilẹ Mokwa, awọn omuwẹ ati awọn akin eeyan to ba le ṣe iranwọ lati maa doola awọn eeyan ti ko ba ti i ku.
Bakan naa ni wọn ni wọn yoo maa gbe awọn to ba ti ku jade.
Atẹjade NASEMA tẹsiwaju, pe eeyan mẹta ti i ṣe obinrin kan ati awọn ọmọde meji lawọn ti doola ẹmi wọn.
Ileewosan ijọba to wa ni Mokwa ni awọn mẹta naa wa bayii bi NASEMA ṣe wi, wọn n gba itọju fun ijaya to mu wọn ati ara ti wọn fi ṣeṣe.
Ni ti awọn ti wọn ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ajọ yii sọ pe oku eeyan mọkanlelogun (21) ni awọn gbe jade.
Ṣugbọn iroyin to gbode bayii ni pe o ti le ni oku ọgọrun-un (100) ti wọn gbe jade latari ijamba naa.
Ninu ọrọ olori agbegbe Mokwa, Muhammad Shaba Aliyu, o ni o ti le ni ọgọta ọdun (60), ti iru iṣẹlẹ bayii ti waye gbẹyin.
O rọ ijọba lati ran wọn lọwọ ni gbogbo ọna.
Iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii, a o maa mu iroyin wa bo ba ṣe n lọ.