Olufunke Hassan tún gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ f’áwọn àgbàlagbà

Olufunke Hassan tún gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ f’áwọn àgbàlagbà

Yínká Àlàbí

Alaga ijọba ibile idagbasoke Onigbongbo ti n pa itu meje t’ọdẹ n pa ninu igbo lati gba ti o ti gba ọpa asẹ alaga Onigbongbo. O pin ẹbun l’ọdun keresi, o mu inu ara ilu dun l’ayajọ ọjọ ololufẹ, o san owo JAMB awọn ọmọ ọọdunrun, o da ọpọ ọna l’ọda, o sọgbo d’ile, o s’ọgbẹ digboro koda awọn ọlọpaa jẹ ninu mudun-mudun ijọba awa-ara-wa naa, o kọ agọ ọlọpaa igbalode fun wọn ni Oregun.
Pabanbari tun wa sẹlẹ ni ọjọ Satide, ọjọ karun-un, osu keje ọdun 2025 yii nigba ti wọn tun si iwe kan awọn agbalagba. Ijọba Onigbongbo ya ọjọ naa sọtọ fun awọn agbalagba. Wọn ko gbogbo ohun to le maye rọrun fun wọn lọjọ naa ati lẹyin ọjọ naa wa si ipagọ naa to wa ni Dr Abayomi Finni, Opebi Link Bridge, Ikeja.
Hon. Bisi Anifowose to je akọwe agba fun alaga lo kọkọ side eto nigba to n salaye idi ti awon fi gbe eto naa kalẹ. O ni awọn mọ pe agba soro da, O ni ko rọrun lati dagba, eyi to tumọ si pe ẹni ti Ọlọrun ba fun ni oore ọfẹ lati dagba ni lati toju ara rẹ.
Alaga ijọba ibilẹ, Hon. Olufunke Rekiya Hassan lo wa sisọ loju eegun pe awọn ko gbọdọ ma fi tagba se nitori pe “ ko si bi ọmọde se le lasọ tuntun to, ko le lakisa to agba”. Alaga ni ọpẹlọpẹ ọla awọn agba ati ti Ọlọrun ni awọn fi n se’jọba. Awọn ni onilu to wa labẹ odo to n lu fawọn jo. Awọn ni Ọlọrun fi se ejika ti ko jẹ ki asọ yẹ lọrun awọn. Alaga ni awọn ni wọn mọ ibi ti igi ti awọn n ge loko maa wo si. Eyi ni ko le jẹ ki awọn ko iyan wọn lai f’ewe rabata boo.
Dokita Olaniyan lati ile iwosan Oregun ni o ti koko la awon agbalagba lọyẹ bi o se yẹ ki wọn maa se itọju ara wọn. O gba wọn nimọran lati din ounjẹ gaaki ku, ki wọn maa jẹ eso daadaa, ki wọn din maggi ati iyọ ku ninu ounjẹ, ki wọn bẹrẹ si maa sọ ounjẹ jẹ, ki wọn maa se iru ere idaraya ọjọ naa nitori pe awọn lo ba ọjọ ori wọn mu, ki wọn maa wo ere tabi se ere to n mẹrin tabi awada dani, ki wọn ni ibasepọ to dan mọran pẹlu awọn alabagbe wọn, ki wọn ma se maa da gbe inu ile, ki wọn si maa loogun wọn deede fun awọn to ba ti wa lori oogun, ki wọn maa bẹ ile iwosan wo loorekoore nitori pe ọfẹ ni ile iwosan ijọba bẹẹ ni  arabinrin yii si tun gba wọn nimọran lati ma se lo oogun ti awoọ dokita tabi nọọsi o fọwọ si.
Ara awọn ere idaraya ti ijọba ibilẹ Onigbongbo ko wa fun wọn naa ni ere ayo tita, ludo tita, kaadi tita, draft tita, aro dida, aworan yiya, amọ̀ ati ijo jijo ti ko ni pakaleke ninu. Ijo jijo pẹlu orin Wasiu Ayinde ati ti Oloogbe Ayinle Omowura ni wọn fi kadii eto fun awọn agbalagba naa nilẹ.
Ijọba ibilẹ idagbasoke Onigbongbo seto owo, ounjẹ ranpẹ pẹlu eso lorisiirisii fun gbogbo awọn agbalagba naa lati le jẹ ki wọn mọ iru ounjẹ ati eso to dara fun ara wọn.
Lara awọn majẹobajẹ to pejupesẹ si ibi ipagọ naa ni adari eto Abilekọ Shoye Samiat to wa lẹka iroyin ati igbohun safẹfẹ ni Onigbongbo, awọn naa ni igbakeji alaga Prince Taofeek Olorunfunmi, Dr  Abdulganiyu Oluremi, Dr Abayomi Finnih,Barr. Sanya, Chief Muyibi Rufai, Chief Odofin, Dr Yinka Olajide, Alagba Wasiu Lawal, Alagba Musbau Ishola, Akogun Kola Onadipe, Alagba Ben, Alagba Tunde Animashaun, Prince Orimolade, Hon Waheed Sodeeq, Ẹkẹrin Onigbongbo, Olori ẹya Ibo ni Onigbongbo ati awọn eniyan nla nla miiran lo ro wamu si ibi ipagọ naa.