Ọlọ́pàá ri òkú ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n gún pa nínú ilé ní Amẹ́ríkà

Odunsi
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti ṣàwárí òkú ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ Britain àmọ́ tó ní orírun Nàìjíríà, Elizabeth Tamilore Odunsi nínú yàrá rẹ̀ ní Houston, Texas.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Houston àti àwọn ẹbí ọmọbìnrin náà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa nọ́ọ̀sì ní Amẹ́ríkà sọ pé ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ló kù kí Tamilore parí ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà tó wáyé.
Ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin ni wọ́n bá òkú Tamilore nínú yàrá rẹ̀ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá já ilẹ̀kùn àbáwọlé rẹ̀.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ojú ọgbẹ́ ọ̀bẹ pọ̀ lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá nílẹ̀ ilé rẹ̀. Bákan náà ni wọ́n bá ọkùnrin míì tó wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run pẹ̀lú ojú ọgbẹ́ ọ̀bẹ lára tirẹ̀ náà, tí wọ́n sì ti gbe lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Tamilore, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23), tí ìkànnì ojú òpó rẹ̀ lórí TikTok ń jẹ́ Tamidollars máa ń kọ ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní US fáwọn ẹgbẹ̀rún ọgbọ̀n tó ń tẹ̀le lójú òpó náà.
Ní ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹrin ni Tamilore fi fídíò sórí ojú òpó TikTok rẹ̀ kẹ́yìn, tó sì sọ pé ọ̀sẹ̀ méjì ló kù fún òun láti parí ẹ̀kọ́ òun.
Ó ní òun yóò lọ fún ìsinmi lẹ́yìn tí òun bá parí ẹ̀kọ́ náà tán àti pé òun ti gba ààyè ìsinmi òun kalẹ̀.
Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìkówójọ láti gbé òkú rẹ̀ padà sí UK fún ètò ìsìnkú tó yẹ fún-un tí wọ́n sì ti rí owó tó tó £44,000 ($58,000) lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Ẹ̀gbọ́n Tamilore, Georgina Odunsi kọ síbi ìkànnì ìkówójọ náà pé Tami jẹ́ onínú ire àti oníwà tútù.
“Ó kúrò ní UK lọ sí United States láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ nọ́ọ̀sì ní ìfarajìn sí ṣíṣe ìtọ́jú àwọn èèyàn.”
Ó fi kun pé àdánú ńlá ni pé wọ́n dá ẹ̀mí Tamilore légbodò nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ kó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga pàápàá ní àsìkò tó yẹ kó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun àti ọjọ́ iwájú tó dára fún-un.
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Houston ṣe sọ, nǹkan bíi aago mẹ́ta àbọ́ ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n ni wọ́n gba ìpè láti ilé àwọn Tamilore.
Àwọn kan ilẹ̀kùn àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni tó dáhùn. Ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n rí níbi àbáwọlé ilé náà ló mu wọn já ilẹ̀kùn wọlé.
Àwọn ọlọ́pàá náà sọ pé àwọn bá òkú Tamilore ní yàrá ìdáná pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú ọgbẹ́ ọ̀bẹ lára rẹ̀, táwọn sì tún rí ọkùnrin míì pẹ̀lú ojú ọgbẹ́ ọ̀bẹ kan lára rẹ̀ ní yàrá míì.
Wọ́n ní Tamilore ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ káwọn tó dé ibẹ̀.
Ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Texas Woman’s University tí Tamilore ti ń kẹ́kọ̀ọ́ kò fèsì sí ìbéèrè BBC News lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Nínú fídíò kan tó ṣe lọ́dún tó kọjá, Tamilore sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi fẹ́ràn láti máa gbé ní US dípò UK.
Láìpẹ́ yìí ni ó fi àwòrán aṣọ àti fìlà tó fẹ́ lò lọ́jọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde rẹ̀ sórí TikTok pẹ̀lú àkọ́lé pé ó ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.
Ṣáájú ni ó ti fi àwọn fídíò bí ó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sórí ìkànnì náà pẹ̀lú àkọ́lé pé “mi ò tíì mọ̀ ọ́n báyìí àmọ́ tó bá máa fi tó ọdún kan sí àsìkò yìí gbogbo ìgbìyànjú mi ló máa já sáyọ́, mo máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí nọ́ọ̀sì ní ẹ̀ka tó wù mí.”
Ó ní òun gbà á léró lái ní ìbáṣepọ̀ tó dára pẹ̀lú Kristi, gbígbé ìgbéayé àlááfíà láì sí ariwo.