Òkúta olówo iyebíye tó jàbọ̀ láti ojú ọ̀run Mars sórílẹ̀ ayé di títà ní $4.3m
Fẹ́mi Akínṣọlá
Òkúta Mars kan tí wọ́n ní irú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n – tó sì jẹ́ pé òhun lo tọbi jùlọ tí wọ́n máa ṣàwárí ní orílẹ̀ ayé – ni wọ́n ti tà ní owó iyebíye $4.3m ní New York lọ́jọ́rú.
Òkúta náà tó jábọ́ láti ojú ọ̀run Mars ni wọ́n pè ní NWA 16788. Ó wúwo tó ìwọ̀n kílógíráàmù mẹ́rìnlélógún àbọ̀ (24.5kg) tó sì gùn ní ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà méjìdínlógójì àti ọwọ́ kan (38.1cm) gẹ́gẹ́ bí Sotheby’s ṣe sọ.
Ẹkùn kan ní orílẹ̀èdè Niger ni wọ́n ti rí òkúta náà nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2023.
Ó tóbi ní ìdá àádọ́rin (70%) ju òkúta Mars kankan tí wọ́n tí i rí lórílẹ̀ èdè ayé lọ gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ Sotheby’s tó ṣe agbátẹrù títà rẹ̀ ṣe sọ.
Sotheby ṣe àpèjúwe òkúta náà, èyí tó fẹ́ fi ara jọ àwọ̀ pupa, bí ohun tí kò wọ́pọ̀ rárá. Bíi irinwó àwọn òkúta yìí ni wọ́n ti ṣàwárí ní òde ayé.
“Èyí ni òkúta Mars tó tóbi jùlọ tí a máa rí láyé. Ó ṣòro láti ri kí irú rẹ̀ jàbọ̀ láti ibẹ̀yẹn síbí,” Cassandra Hatton, igbákejì alága tó ń rí sí ọ̀rọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìtàn àwọn ohun àlùmọ́nì ní iléeṣẹ́ Sotheby’s sọ nínú fídíò kan tí wọ́n fi sórí ayélujára.
“Ẹ rántí pé ìdá àádọ́rin ni omi tó yí ilé ayé ká. Fún ìdí èyí, oríire ńlá ló jẹ́ pé orí ilẹ̀ ni òkúta jàbọ̀ sí tí kìí ṣe láàárín omi, èyí tó ṣeéṣe ká ṣàwárí rẹ̀ níbẹ̀ náà.”
Ibí tí òkúta náà yóò padà sọlẹ̀ sí kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni nítorí gbogbo ìròyìn àti ìmọ̀ nípa títà rẹ̀ yóò wáyé lábẹ́nú.
Àlékún owó orí àti gbogbo owó tí wọ́n ná le lórí jẹ́ kí àpapọ̀ iye rẹ̀ jẹ́ $5.3m, Sotheby’s sọ.
Níbi ètò ọjà títà náà tó wáyé lọ́jọ́rú, àwọn ọjà tó lé ni ọgọ́rùn-ún ló wà lórí àtẹ tó fi mọ́ egungun ẹranko Ceratosaurus tó ti kú kan tí wọ́n tà ní $26m àti egungun orí Pachycephalosaurus kan tí wọ́n tà ní $1.4m.