Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Oga Olopaa yan-an-yan-an, Alkali Bba

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.

Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ó tó gba 270,000 Naira lọ́wọ́ ọ rẹ̀, nitori ikorita Bódìjà Ojúurin.

Ṣaájú ni àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára kan ti sọ pé ọkùnrin nà kú nítorí ọgbẹ́ ìbọn tí ó wọ̀ ọ́ lára.

À mọ́ ASP Òsífẹ̀sọ̀ sọ pé ẹ̀mí ọkùnrin ọ̀hún kò bọ́, tó sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ níléèwòsàn kan.

Òsífẹ̀sọ̀ sọ pé ìwádìí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fihàn pé àwọn adigunjalè náà tọ ipasẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Ibrahim láti ibì kan tó ti lọ̀ ọ́ ta ọjà nínú ìgboro Ìbàdàn, tó sì ń padà sí ibùgbé rẹ̀ ọjà Akinyele, níjọba ìbílẹ̀ Akinyele.

“Nítorí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ tó wà nì òpópónà márosẹ̀, Ibrahim pinnu láti gba ọ̀nàaàbùjá kan tí kìí ṣe ibi tí ọ̀pọ̀ èèyà ń gbà. Ibẹ̀ ni àwọn adigunjalè náà ká a mọ́.

“Láti orí ọ̀kadà tí wọ́n wà, ni wọ́n ti yìnbọn mọ́ Ibrahim ní àwọn ìka ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n tó ó gba owó tó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀.”

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìwádìí ti ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú ọ̀hún.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here