Ọkùnrin kan jábọ́ láti orí ilé Cocoa House ní ilù Ibadan 

Ọkùnrin kan jábọ́ láti orí ilé Cocoa House ní ilù Ibadan

Mary Fágbohùn

Ọkunrin kan ti enikan ko mo ni won so pe o jabọ silẹ lati ori aja Ile gogoro Cocoa House to wa ni agbegbe Dugbe, ni ilu Ibadan, ni ipinlẹ Oyo.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu karun-un, ni arakunrin naa jabọ ni Cocoa House, ile to ni aja mẹrindinlọgbọn, to si ti fi igba kan ri jẹ ile to ga ju ni ilẹ Afrika.

Iṣẹlẹ yii mu ki idiwọ ati idaduro ba ọpọ ile itaja ati awọn okowo to wa ni agbegbe naa.

Ọkan ninu awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju re, sọ fun awọn oniroyin pe, oun ro pe ẹyẹ nla lo n jabọ lati oke, lai mọ pe eniyan ni.

“Nigba ti eni ọhun balẹ ni mo ri pe eniyan lo jabọ.

“Mo ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ mi lọwọ ṣugbọn mi o le gba iṣẹlẹ naa silẹ nitori bi ẹru ṣe ba mi.”

Ẹlomiran tun sọ pe “ẹni naa ti kọkọ balẹ si ori orule awọn ẹsọ alaabo, ki o to di pe o balẹ. Iṣẹlẹ iyalẹnu nla ni.”

Ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ni ẹnikan ko ti mọ ṣugbọn iroyin jabo pe, iwadii ti bẹrẹ lori rẹ.

Ileeṣẹ Odu’a Investment Company Limited, to n mojuto Cocoa House, ti fi atẹjade sita fun awọn oniroyin lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ni ilu Ibadan.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọhun, Victor Ayetoro, ninu atẹjade to buwọlu sọ pe ẹni to ṣubu yii ni awọn ti gbe lọ si ile iwosan bayii, to si ti n gba itọju.

“Iṣẹlẹ yii dun wa pupọ ṣugbọn a n fi da awọn araalu loju pe a o ṣe iwadii lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.”

Cocoa House ni ile alaja gogoro, awo ṣi fila akọkọ ni orilẹ ede Naijiria ati ni Iwọ oorun Africa.

Oṣu Keje, ọdun 1964 ni wọn kọ ọ tan, amọ oṣu Keje ọdun 1965 ni wọn ṣi i .

Ijọba ẹkun Western Region lo kọ Cocoa House, labẹ idari Oloye Samuel Ladoke Akintola.

Ile alaja gogoro naa ga ni iwọn mita marunlelọgọrun-un, to si ni aja mẹrindinlọgbọn.

‘Ile Awọn Agbẹ’ ni orukọ ti wọn kọkọ sọ Cocoa House. Ṣugbọn wọn yi orukọ naa pada si Cocoa House, nitori pe ere ti wọn ri lati ara koko tita si ilẹ okeere, ni wọn fi kọ ọ

Lasiko naa, Cocoa House jẹ nnkan iwuri ati amuyangan fun awọn olugbe ilu Ibadan ati Naijiria lapapọ.