Ojú ogun le ní ọ̀nà márosẹ̀ Lagos/Ibadan

Ojú ogun le ní ọ̀nà márosẹ̀ Lagos/Ibadan

Ìròyìn òwúrọ̀

Ẹni ti ko ba pọn dandan fun lati jade, to ba seesi jade si ọna marosẹ Eko si Ibadan lonii ma kabaamọ.
Wọn ni nnkan bii aago mẹrin aabọ idaji oni ni ijamba mọto sẹlẹ ni ọna naa.
Mọto Tipa yẹpẹ kan da silẹ ni aarin ọna ni ori biriiji Otedola gangan, loke re diẹ ni tirela to ko apo nnkan bii fulawa burẹdi naa da gbogbo re silẹ. Wọn wa fi ọna tooro silẹ fun awọn mọto to ba n lọ si Eko.
Nigba to fi maa di bii aago kan aabọ ọsan gbogbo ọna lati lọ ati lati bọ ti fọpọ. Gbogbo rẹ ti di pa. Awọn kan ni ijamba mọto miiran tun sẹlẹ ni ọna lati lọ si Ibadan. Eyi wa jẹ ki gbogbo rẹ nira fun ẹni to fi wakati mẹta rin laaarọ to tun lo mẹta miiran lalẹ ni oni ọjọ kẹtalelogun, osu kin-in-ni ọdun yii.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here