Ọjọ́ tí fọ́ọ̀mù JAMB títà máa dópin àti ọjọ́ ìdánwò
Yínká Àlàbí
Ajọ JAMB to n se kokari idanwo asewọle si ile iwe Fasiti kaakiri orileede yii ti kede lori ẹ̀rọ ayelujara X wọn ni ana ọjọ isẹgun, eyi jẹ pẹlu asẹ ọga patapata ajọ naa, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede.
Ajọ naa ni fọọmu tita maa bẹrẹ si ni wa ni gbogbo ọfiisi awọn to n taa lati ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kin-in-ni ọdun yii (26/01/2026) titi di ọjọ kejidinlọgbọn osu keji ọdun yii (28/02/2026).
Awọn ọjọ idanwo si maa jẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹrin ọdun yii (17/04/2026) titi di ọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹrin ọdun yii (25/04/2026).
Ajọ JAMB fi kun pe akẹkọọ to lẹtọọ si idanwo naa gbọdọ pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni ọgbọn ọjọ osu kẹsan-an ọdun yii (30/09/2026).
JAMB ni ọmọ ti ko ba ni pe iye ọdun naa gbọdọ jẹ ọmọ to mowe gan-an. Ọjọgbon Oloyede ni “o ni leta ti o maa ko si ajọ JAMB, o si gbọdọ gba maaki ida ọgọrin ninu ọgọrun-un (80%) gbogbo isẹ to ba se”.









